Nkechi Blessing: Ọ̀rọ̀ ọkọ mí, ọkọ mí tí àwọn Yoruba ma ń pe àfẹ́ṣònà ló kó bá mi

Nkechi Blessing

Oríṣun àwòrán, Nkechi Blessing

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gbajugbaja oṣerebinrin, Nkechi Blessing ti tọrọ aforiji lọwọ awọn ololufẹ rẹ fun bi o ṣe pa irọ wi pe oun ṣe igbeyawo pẹlu ọrẹkunrin rẹ, Opeyemi David Falegan.

Blessing sọ ni oju opo rẹ ni oun ko ṣe igbeyawo pẹlu Falegan nitori naa ko si ọrọ lọkọ laya ni ọrọ wọn.

Ninu akọjade loju opo Instagram rẹ to safihan ibanisọrọ laarin awọn mejeeji ni o ti sọrọ bẹẹ.

Nkechi Blessing

Oríṣun àwòrán, Instagram/Nkechiblessing

Àkọlé fídíò, 'Mo kọ́kọ́ máa ń ro Amala mi fáwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́fẹ̀ẹ́ l'Amẹ́ríkà kí ojú mi tó ṣí tó ń já owó gidi fún mi báyìí'

Nibẹ ni Nkechi Blessing ti beere lọwọ ẹni to n ba sọrọ naa wi pe ṣe awọn fi igba kan ṣe igbeyawo ni? ṣe oun jẹ iyawo rẹ ni?

Amọ ẹnikeji naa dahun pe oun ko ri pe ẹlomiran le jẹ iyawo oun gidi bii Nkechi nitori o mu ki aye oun dara si ju ti atẹyinwa lọ, amọ nibayii o dabi ẹni pe o fẹ da okunkun sii.''

Esi ti Nkechi fun un ni pe ki eniyan kuro ninu ibanidọrẹ laarin akọ si abo ko tunmọ si pe opin aye ni tabi okunkun su bo gbogbo nkan.

Àkọlé fídíò, Samuel Ajirebi ọmọ ọdún mẹ́rin àtijọ́ rèé, ó bojú wo fíìmù rẹ̀ ní kékére, máàkì tó fún ara rẹ̀ rèé

''Maa fi eleyii sita nibi nitori ọjọ ọla, ọrọ awọn Yoruba to ma n pe afẹsọna ni ọkọ mi, ọkọ mi lo fa eleyii''

''Nitori naa ODF gbe orukọ mi kuro ni ẹnu rẹ nitori ẹmi fun ara mi lo kuro ninu ibanidọrẹ yii''

Àkọlé fídíò, Jimi Solanke: Bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ eré òṣùpá láyé àtijọ́ táa mú ìtàn Yorùbá sísọ dé America padà

''Mo tọrọ aforiji lọwọ gbogbo awọn ti wọn rope tọkọtaya ni wa, ko si ohun to jọ bẹẹ, emi ni mo fa a, ẹma binu.''

Nkechi Blessing wa kesi Falegan lati fi silẹ nitori oun ko ni jẹ ki ẹnu sii ti ko ba jawọ ninu ọrọ oun.

Mi o lè sọkún torí ǹkan ọkùnrin tí kò lè gbò mí jìgì-jìgì ju ìṣẹ́jú àáyá méjì lọ - Nkechi Blessing

"Aimoye nkan iṣere ibalopọ ti mo ko jọ soke loriṣiriṣi, mi o le layelaye sunkun tori airi ibalopọ pẹlu ọkunrin".

''Mo nifẹ rẹ tori tọrun, iwọ nikan ni eera to wa ninu Suga mi, mo dupẹ gbogbo nkan to n ra fun mi too fi n ba mi jẹ yii ''

Nkechi Blessing ati Falegan

Oríṣun àwòrán, Nkechi Blessing Sunday

Awọn ọrọ to maa n kun oju opo ayelujara Nkechi Blessing ree ni bii oṣu melo kan sẹyin.

Amọ nibayii, awọn ọrọ bii "mi o nilo ibalopọ pẹlu rẹ, ko ni kọbọ lọwọ ko tun le ṣe ju iṣẹju mẹrin lọ lori bẹẹdi" lo n ti ẹnu Nkechi jade ninu fidio to fi sita.

Àkọlé fídíò, Olaiya Igwe ló wá ra epo níbi tí mo ti ń di "nussle" epo mú mo bá bẹ́ mọ́ ọ́, bí ayé mi ṣe yí padà di òṣèré fíìmù rèé

Ki lohun to wa mu iyipada wa ninu ọrọ ti ṣere yi n kọ sita. Nibo ni nkan ti bẹrẹ si ni laarin oun ati ololufẹ rẹ?

Ọkọ Nkechi Blessing, Opeyemi David Falegan lo kọkọ kede pe tirela ti gba aarin oun ati iyawo oun gidi gan ko si si nkankan to da awọn pọ mọ.

Nkechi Blessing ninu oyun ati Falegan

Oríṣun àwòrán, Nkechi Blessing Sunday

Loju opo Instagram rẹ l'Ọjọru ọsẹ lo ti n fi ẹsun kan Nkechi pe onibalopọ abosabo ni o jẹ ati pe oun ko fẹ ni nkan ṣe pẹlu iru eeyan bẹẹ.

"Mi o ki n ṣe ọkọ ẹnikẹni, mi o fẹ ki wọn mọ mi pẹlu onijagidijagan eeyan tabi ọrọ ija kankan bi ko ṣe awọn to n tun aye awọn eeyan ṣe".

Opeyemi ni oun ko fẹ nkankan to maa ba iṣẹ ire ti oun ti ṣe silẹ jẹ.

"Mo ni orukọ ti mo n gbiyanju ati daabo bo. Mi o fẹ ohunkohun to jọ ki wọn maa sọ pe ọkọ...".

Ki ni Nkechi Blessing sọ?

Nigba ti oṣere Nkechi naa yoo gbe fidio tirẹ jade, lo ba kẹnu bọ ọrọ to gbe e gbona gidi gan fun Falegan.

O ni gbogbo oṣu mẹta ti oun lo pẹlu rẹ nigba to lọ si London ko si iṣẹ kankan to n ṣe ju pe o kan n sun to o n ji ni.

Àkọlé fídíò, Bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn akẹgbẹ́ mi tó jóná nínú ọkọ̀ jáde, ṣe lara wọn ń bó, wọ́n ń tẹ́ wọn s'atẹ́gùn - Akẹkọ̀ọ́ Akungba

"Mi o lè máa sọkún torí ǹkan ọkùnrin tí kò lè gbò mí jìgì-jìgì jú ìṣẹ́jú àáyá mẹ́rin lọ". Ni Nkechi ba ni ki awọn araale duro, ohun fẹ lọ fi awọn nkan iṣere ibalopọ ti oun fi n gbọ tara oun han wọn loke, afi to ṣi baagi to ko awọn kini ọhun jade.

Bakan naa ni Nkechi ni Falegan kan n lo oun lati fi di ilumọọka eniyan. O ni ayederu ni igbe aye ti o n gbe kiri to kan n sun to n ji lori fidio ori ayelujara lasan.

Ṣe lootọ ni wọn ṣe igbeyawo?

Nkechi to jẹ pe o kede igbeyawo oun ati Falegan ni ọjọ Kẹwa oṣu Kẹfa ọdun 2021 jade ninu nkan to sọ sita lori Instagram pe ara nkan ti irẹpọ oun pẹlu ọkunrin yii ṣe fun oun ni pe awọn ti wọn ro pe oun ti ṣegbeyawo amọ ti wọn fẹ ran oun lọwọ n bẹru lati sunmọ oun. "Mi o le maa jiya ki n tun maa rẹrin musẹ".

Nkechi fi awọn fọto igbeyawo oun ati oloṣelu to jẹ ọmọ ipinlẹ Ekiti naa sita lọjọ ibi Falegan.

Nkechi ni tori pe Falegan rii pe oun ti fii silẹ lo ṣe lọ n sanwo fun awọn oniroyin irọ ki wọn maa gbe iroyin atijọ jade nipa oun.

Nkechi fọ sẹkun pe awọn oniroyin naa fẹ ba aarin oun ati alaanu ti Ọlọrun kan ran si oun toun o si ni nkankan pọ pẹlu rẹ jẹ ni. O ni iṣẹ lo pa awọn pọ.

Nkechi Blessing ati Falegan

Oríṣun àwòrán, Nkechi Blessing

Awọn to fẹ ran mi lọwọ n bẹru lati sun mọ mi

"O le fẹran eeyan koo si tun ja wọn ju silẹ,,,, Jaye ori ẹ fun asiko ranpẹ to ku koo si pada si igbe aye alaini nkan too wa tẹlẹ. O ro pe o ti ri ẹja arọ gbe abi? Emi ti mo ṣi n bẹ Ọlọhun, o wa fẹ sọ mi di onibara tori iṣẹ akanṣe to n ṣe kiri".

Nkechi ni nkan to ku ti Falegan yoo fẹ sọ ni pe oun ti ba gbogbo aye sun tan amọ to ni oun ṣi wa digbi pe Falegan gan mọ sii to maa n yaa lẹnu pe nkan ọmọbinrin oun ṣi di pa, amọ oun gba to ba pe oun ni Olosho.

Nkechi bu ẹnu atẹ lu iroyin to n lọ kaa kiri pe ọkọ rẹ kọ ile fun un. O ni owo ti oun n ri latara awọn iṣẹ ori ayelujara ti oun n ṣe loun fi kọ ile.

Ẹwẹ, gbajugbaja oṣere naa ni oun yoo gbọ si awọn to n gba oun nimran lati dakẹ lẹnu.

Ohun tawọn eeyan n sọ loru ayelujara

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Esi Awọn eeyan lori ayelujara

Oríṣun àwòrán, LindaIkeji

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Esi Awọn eeyan lori ayelujara

Oríṣun àwòrán, Nkechi Blessing