Tontoh Dike, Kpokpogri bẹ̀rẹ̀ sí ní dọ̀tí ara wọn, ẹ wo pabanbarì tó tún rú èyí jáde

Tonto Dike ati ololufẹ rẹ tuntun

Oríṣun àwòrán, InSTAGRAM

Gbajugbaja oṣerebirin Tonto Dike ati ololufẹ rẹ tẹlẹ tun ti n kona ija laarin ara wọn.

Igba akọkọ kọ niyi ti iru gbas gbos yii yoo waye laarin Tonto ati ọmọba Kpokpogri.

Tuntun to ṣẹ tun bẹrẹ yii n waye lẹyin ọsẹ meji ti wọn kede lori ayelujara pe tirela ti gba aarin awọn.

Lati igba naa, ko sẹni to gbọ tabi ri nkankan latọdọ awọn mejeji ayafi to tun di ọjọ Aiku to kọja yii.

Ọrọ wọn pari si agọ ọlọpaa nigba ti oṣerebinrin naa lọ fi ẹjọ sun nipa Kpokpogri.

Àkọlé fídíò, Seye Malaolu: Bí mo ṣe rí àgbára ẹ̀jẹ̀ tó kúnlẹ̀, mò ń bèrè pé ṣé wọ́n pa Turkey níbí ni,

Ki lo fa ija tuntun yii?

Ija to ṣẹṣẹ tun bẹ silẹ laarin awọn ololufẹ mejeji yii bẹrẹ lẹyin ti Tontoh Dike fi fidio kan sita loju opo Instagram rẹ ninu eyi ti Kpokpogri tin n jo.

Ko tun pẹ si eyi ni oṣerebinrin yii ṣe apejuwe ololufẹ rẹ tẹlẹ yii gẹgẹ bi "ẹni ti nkan ọmọkunrin rẹ jẹ anfani adugbo".

Atẹjade Tonto Dike

Oríṣun àwòrán, Tonto Dike/Instagram

Bakan naa lo tun fi ẹsun kan pe Kpokpogri n ba aburo oun lajọṣepọ.

Amọ ninu esi ti Kpokpogri fi sita, oun funra rẹ gba pe "anfani adugbo ni nkan ọmkunrin rẹ" ṣugbọn o sọ fun Tonto pe ko lọ "wa alafia pẹlu Ọlọrun lori gbogbo igbe aye idọti to ti gbe".

Ọrọ yii ti di ranto bayii ti awọn gbajugbaja mejeji si ti bẹrẹ si ni sọrọ si ara wọn lori ayelujara bakan naa lawọn ọmọ Naijiria ti sọ ọrọ wọn di eyi ti wọn n gba bi ẹni n gba igba ọti.

Ki la mọ nipa Prince Kpokpogri?

Kpokpogiri

Oríṣun àwòrán, Instagram/Kpokpogiri

Prince Kpokpogri jẹ oloṣelu ọmọ Naijiria lati ẹya Isoko, ipinlẹ Delta.

Wọn bi i ni ọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹfa ọdun 1978.

Yatọ fun pe o jẹ oloṣelu, o tun jẹ ajafẹtọ lodi si iwa jẹgudujẹra.

Asiko ti orukọ rẹ gbode kan ni igba to ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ lọdun 2021 lẹyin ti iroyin gbee pe oun ni ọkunrin tuntun to wa ninu aye Tonto Dike.

Lara ohun taa ko jọ loju opo Instagram rẹ, Kpokpogri jẹ ẹlẹyinju aanu pẹlu bo ṣe fi aworan awọn ọmọ ile ẹkọ to fi ẹkọ ọfẹ ṣaanu fun.

Bakan naa, o ti gba ọpọlọpọ ami ẹyẹ ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Fake pastors:

Ta ni Tonto dike?

Tonto Dike

Oríṣun àwòrán, Instagram- Tonto Dike

Gbajugbaja oṣere ni Tonto Dike amọ ti ẹnu kii ṣi lori rẹ lọ pọ igba.

Bakan naa, olorin ni, onkọwe ati ajafẹtọ si ni pẹlu.

Oun ni ọmọ ikẹta Ọgbẹni Sunday ati Iyaafin Veronica Dike am iya rẹ ku nigba to wa lọmọ dun mẹta.

Ilu Port Hacourt lo ti dagba to si kawe gboye ni fasiti ipinlẹ Rivers.

Tonto bẹr ere itage ldun 2006 lẹyin to kopa ninu eto agbelewo kan "Next Movie Star lọdun 2005.