Yahaya Bello Campaign DG: Ọmọ Nàìjíría faraya lórí àfiwé tí ọmọ MKO ṣe láàrín ìpolongo ààrẹ bàbá rẹ̀ àti ti GYB

Aworan Gomina Yahaya Bello ati MKO Abiola

Oríṣun àwòrán, Yahaya Bello/Hafsat Abiola Costello

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

"Kii ṣe tori owo ni mo fi fẹ dari ipolongo ibo Yahaya Bello, ifarajin rẹ to ni bii ti baba mi lo mu mi ṣe bẹẹ.

Esi ree ti arabinrin Hafsat Abiola-Costello fọ ni idahun si ibeere wi pe ki lo muu jẹ ipo adari igbimọ ipolongo idibo aarẹ Gomina Yahaya Bello.

Costello ni afiwe pọ laarin baba oun MKO Abiola ati Gomina Yahaya Bello ipinlẹ Kogi.

Moshood Kashimawo Abiola lo jẹ ogunagbongbo oloṣelu ti wọn wọgile ijaweolubori rẹ ninu idibo aarẹ ọdun 1993 ni Naijiria.

Abiola tun jẹ eekan oloṣelu ilẹ yoruba ti gbogo agbaye n wari fun nipa ṣiṣe oṣelu Naijiria.

Apejuwe to ṣe yi lo mu ki awọn ọmọ orileede Naijiria kan faraya wipe o fọwọ ẹrẹ gba gbogbo awọn to dibo yan Abiola pẹlu ọrọ to sọ yi.

Loju opo Twitter awọn to fesi si ọrọ rẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin Naijiria Arise News ni ko mọ nkan to n sọ.

Ninu akọsilẹ itan Naijiria igba akọkọ ree ti wọn yoo fi obinrin jẹ oludari igbimọ ipolongo oludije ipo aarẹ ṣugbọn eyi ko mu inu awọn eeyan dun si Hafsat Abiola-Costello.

Ninu awọn ọrọ taa ri ni eleyi ti Esheza junior@Okeyjunior sọ to fi bẹnu atẹ lu Costello.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

David Azuh C.A naa pẹlu ninu ibẹnu atẹ lu igbesẹ ati ọrọ ti Costello sọ yi.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Bẹẹ naa ni Lah Soliu Olanrewaju ni idojuti nla ni bo ṣe fi Yahaya Bello we Abiola

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí pọ́ọ̀sì “customer” tí mi ò mọ

Iru apejuwe wo gaan ni Hafsat Abiola-Costello ṣe to da rugudu silẹ?

Ori eto to waye lori ileeṣẹ amohunmaworan Arise News TV ni Hafsat Abiola-Costello ti sọ fun atọkun eto Reuben Abati pe afiwe pọ laarin baba oun ati Gomina Yahaya Bello.

Koko pataki kan taa ri fa yọ ninu apejuwe ati afiwe MKO Abiola pẹlu GYB ni bi o ṣe ni inu Abiola yoo dun pe Yahaya Bello lo ọrọ ipolongo Hope 93 rẹ.

Ni ọdun naa lọhun ti Abiola dije dupo, Hope 93 dabi orin akunlẹkọ ti awọn alatilẹyin rẹ n kọ Hope 2023 ni adape rẹ ti Yahaya Bello fẹ ṣamulo.

Aworan Hafsat Abiola Costello

Oríṣun àwòrán, Hafsat Abiola Costello

Hafsat Abiola-Costello ni ko si aburu kankan ninu igbesẹ yi nitori iru eeyan ti Abiola jẹ ni Yahaya Bello jẹ.

''Gbogbo nkan to ṣafihan ifẹsẹrinlẹ ijọba awarawa ni Yahaya Bello ati baba mi duro ti.''

''Bi o ba ba Gomina Yahaya Bello sọrọ, waa ri pe ijẹmọniyan maa n jẹyọ ninu iṣesi rẹ nbi ti baba mi MKO Abiola''

Abiola Costello tẹsiwaju pe bi Abiola ṣe kawe gboye imọ iṣiro naa ni Yahaya Bello ṣe kawe gba a.

O fikunun pe bi MKO ṣe kọ lati ni baba isalẹ nidi oṣelu naa ni ti Yahaya Bello ri.

Àkọlé fídíò, 'Láti kékeré mo ti ní ọjọ́ kan lèmi náà ọ́ kọ́ Mọ́sálásí kékeré bíi àwọn bàbá wa'