Yahaya Bello: Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi kéde èròngbà rẹ̀ láti dupò ààrẹ ní 2023

Oríṣun àwòrán, yahaya bello/twitter
Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello ti kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ orilẹ-ede Naijiria lọdun 2023.
Nibi ikede naa to waye ni gbagede Eagles Square nilu abuja lọjọ Satide, ni Gomina Bello ti sọ pe oun yoo mọ le ipilẹ ti Aarẹ Muhammadu Buhari fi lelẹ, lati sọ ogun miliọnu ọmọ Naijiria di olowo tabua 'millionaires', ti yoo ba fi di ọdun 2030.
O ni oun mọ pe lọdun 2012, iroyin ileeṣẹ BBC kan sọ pe ọgọrun miliọnu eeyan lo n gbe ninu iṣẹ ati os\i ni Naijiria. O ni ṣugbọn lọwọlọwọ, iṣejọ̀ba aarẹ Buhari ti din awọn eeyan naa ku si aadọrin miliọnu.
Bello sọ pe eyi tumọ si pe "yiyọ obitibiti miliọnu ọmọ Naijiria kuro ninu oṣi, ni ọna abayọ si iṣerere orilẹ-ede wa".
"Iṣejọba Yahaya Bello gẹgẹ bi aarẹ, yoo sọ ogun miliọnu di millionaire, ti yoo ba fi di ọdun 2030, pẹlu afojusun pe ẹnikọọkan wọn yoo ró eeyan marun-un miran ni agbara."
- Àṣekẹ́hìn ni yóò jẹ́ fún ẹnikẹ́ni tó bá tún hu ìwà ọ̀daràn ní ìpínlẹ̀ Oyo - Makinde
- Àtẹ̀jíṣẹ́ kan tó wọ orí fóònu mi, ló fi òpin sí ìbànújẹ́ mi lórí ikú Dare ọmọ mi - Adeboye
- "Àwọ̀ ara àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jóná nínú bọ́ọ́sì ń ṣí mọ́ wa lọ́wọ́ nígbà tà ń dóòlà ẹ̀mí wọn"
- Ẹ wo orúkọ àti ojú àwọn èèkànlú tó forí sọta ìkọlù rélùwéè àti ipò tí wọn dì mú
Lara awọn to peju sibi ayẹyẹ ikede naa ni igbakeji olori ile aṣofin, Idris Wase, igbakeji gomina ipinlẹ Kogi, Edward Onoja, ati minisita fun eto irinna oju ofufufu, Femi Fani-Kayode.
Ẹwẹ, nibi eto naa ni Bello ti kede pe ọmọ oloogbe MKO Abiola, Hafsat Abiola-Costello, ni yoo j oludari eto ipolongo ibo oun fun ipo aarẹ.
O ni oun n dije fun ipo aarẹ, nitori awọn iṣẹ ribiribi ti oun ti gbe ṣe nipinlẹ Kogi.
Awọn nkan to yẹ ki o mọ nipa Yahaya Bello
Ọdun 1975 ni wọn bi Yahaya Bello nilu Okenne, nipinlẹ Kogi.
O di gomina ipinlẹ naa ni ọdun 2016, gẹgẹ bi gomina ti ọjọ ori rẹ kere julọ jakejado Naijiria.
Ṣaaju ibo to gbe wọle lọdun 2016, oludije miran, Abubakar Audu, lo n ṣoju ẹgbẹ oṣelu APC. Ṣugbọn, Audu ku ni ọjọ idibo. Eyi si lo mu ki ẹgbẹ fi Yahaya Bello rpo rẹ.
Lẹyin naa lo tun pada dije fun saa keji, to si jawe olubori.
O gbajugbaja lasiko ti aarun Covid-19 wọ Naijiria lọdun 2020.
Bello sọ pe aarun naa jẹ irọ patapata. Bakan naa lo kọ eto ayẹwo, itju ati abẹrẹ ajẹsara fun aarun naa nipinlẹ Kogi.












