Enoch Adeboye: "Daddy, ẹ jẹ́ kí Ọlọrun gbé yín" ní ọ̀rọ̀ tó tú mí nínú kúrò nínú ọ̀fọ̀ ọmọ mi

Oríṣun àwòrán, PAstor E.A Adeboye/Facebook
Pasitọ agba ijọ Reedmed Christian Church of God, Enoch Adeboye, ti sọrọ lori bi ibanujẹ rẹ se dopin nigba ti ọmọ rẹ kan ku lọdun 2021.
Gẹgẹ bi ọrọ to sọ, o ni atẹjiṣẹ kan ṣoṣo ti ẹnikan fi ranṣẹ, lo yi ọkan oun pada, lẹyin ti Dare ku.
Oṣu Karun-un, ọdun 2021 ni Dare Adeboye, to jẹ ẹni ọdun mejilelogoji ku loju orun rẹ nilu Eket, nibi to n gbe nipinlẹ Akwa Ibom.
Ilu naa lo ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bi alufaa kan ninu ijọ Redeem.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Baba Ijesha ń fẹ́ Princess, ìyá Princess gan sọ lójú mi pé kó tọ́jú ọmọ òun dáadáa - Ẹlẹ́rìí Kẹrin
- Lukuluku Bantashi, ọdún 27 lẹ́yìn ikú gbajúmọ̀ aláwàdà
- Àlàyé rèé lórí aìsàn tó pa Dejo Tunfulu àti ilé ìwòsàn tó dákẹ́ sí
- Ikú Dejo Tunfulu ti kó ìrẹ̀wẹ̀sí ọkàn bá mi, ń kò le kópa nínú eré tà ń yà mọ́ - Ọ̀gá Bello
- Mo ti gba ìdúnkookò ikú tórí mo tako ṣíṣí bodè Lekki padà - Mr Macaroni
- Irọ́ ní Atiku, Saraki, Tambuwal àtàwọn yókù ń pa pé àwọn ọ̀dọ́ ló dá N40m owó fọ́ọ́mù ìdíje sípò ààrẹ fún àwọn - Obasanjo
- "Àwọ̀ ara àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jóná nínú bọ́ọ́sì ń ṣí mọ́ wa lọ́wọ́ nígbà tà ń dóòlà ẹ̀mí wọn"
- N kò rí oorun sùn lórí iṣẹ́ ibi àwọn agbésùnmọ̀mí, òògùn oorun gan kò ràn mí - El-Rufai
- "Táyà tírélà tó ta pàù lójijì lo fọ mi loju, di mi leti, o tun ge apa èmi àti ọmọ mi"
Nigba to n sọrọ nibi ipade adura oloṣooṣu ijọ naa fun ti oṣu Kẹrin, Pasitọ Adeboye sọ pe inu ibanujẹ nla ni oun wa lẹyin iku ọmọ oun, Dare.
O ni ṣugbọn nnkan yipada nigba ti ọmọ oun kan ninu igbagbọ, fi atẹjiṣẹ kan ranṣẹ si ori ẹrọ ibanisọrọ oun pe "Daddy, ẹ jẹ́ kí Ọlọrun kí o gbé yín".
O ni ọrọ naa lo yi ọkan oun pada, ti oun fi pa ibanujẹ ti, ti oun si gba ki Ọlọrun gbe oun, nitori pe oun lo ma n ba ẹda gbe iṣoro, ibanujẹ, ati wahala, niwọn igba ti eeyan ba ti jẹ ọmọ rẹ.
Bawo ni iku Dare Adeboye ṣe waye?
Ọjọ Kẹfa, oṣu Karun-un, ọdun 2021, ni iroyin jade pe Dare Adeboye, to jẹ ọmọ kẹta fun Pasitọ Enoch Adeboye ti ku.
Amọ, o ti ku lati ọjọ kẹrin, oṣu Karun-un.
Iroyin sọ pe o sun, ni ko ji mọ ni oru mọju ọjọ naa.
Gẹgẹ bi ikede ti ẹbi fi sita, oloogbe naa ko ṣaisan, tabi ni aarun kankan ṣaaju iku rẹ.
Eyi ti iroyin sọ pe o mu ki awọn agba alufaa inu ijọ naa gba adura kikan, pe boya yoo ji pada, niwọn igba ti ko ṣaisan tẹlẹ.
Akọsilẹ diẹ nipa Dare Adeboye
Wọn bi Dare Adeboye ni ọjọ kẹsan an, oṣu Kẹfa, ọdun 1979.
Dare jẹ olukọ awọn ọdọ, o si tun jẹ ọkan pataki lara awọn ọdọ to lẹnu lọrọ ati ilumọka ninu ijọ RCCG.
O ti fi igba kan ri ṣiṣẹ gẹgẹ bii Pasitọ lori ijọ RCCG House of Praise, to wa ni Birmingham, nilẹ Gẹẹsi.
Bẹẹ naa lo tun ṣiṣẹ gẹgẹ bii pasitọ ijọ naa, ẹka ti awọn ọdọ to wa ni Ipinlẹ Kaduna.
Ki ọlọjọ to de, oun ni pasitọ gbogbogbo fun awọn ọdọ ni RCCG fun ẹkun Niger, Benue, Kwara, Kogi, Nasrawa, Plateua ati Abuja.


















