Obasanjo: Kò sí ọ̀dọ̀ tó le fi ògòjí mílíọ̀nù náírà ra fọ́ọ̀mù fáwọn olùdíje sípò Ààrẹ

Oríṣun àwòrán, @atiku
Ààrẹ àná lorílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo ti ṣèkìlọ̀ fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti máse dìbò tàbí ṣe àtìlẹyìn fún àwọn olùdíje sípò Ààrẹ to ba n parọ.
Aarẹ tẹ́lẹ̀ ni naijiria naa ni oludije tó bá ti sọ wí pé àwọn ikọ̀ kan tàbí ẹgbẹ́ kan ló ra fọ́ọ̀mù láti díje sípò Ààrẹ fún àwọn n parọ ni.
Obasanjo sọ èyí níbi ètò ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Pásítọ̀ Itua Ighodalo tó wáyé nílùú Eko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ohun mẹ́jọ pàtàkì nípa Dejo Tunfulu tó jáde láyé
- "Àwọ̀ ara àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jóná nínú bọ́ọ́sì ń ṣí mọ́ wa lọ́wọ́ nígbà tà ń dóòlà ẹ̀mí wọn"
- N kò rí oorun sùn lórí iṣẹ́ ibi àwọn agbésùnmọ̀mí, òògùn oorun gan kò ràn mí - El-Rufai
- Ọ̀rọ̀ Amaechi àti El-Rufai fihàn pé ìjọba lọ́wọ́ nínú ìgbésùnmọ̀mí – PDP
- "Táyà tírélà tó ta pàù lójijì lo fọ mi loju, di mi leti, o tun ge apa èmi àti ọmọ mi"
- Ìgbésẹ̀ yíyan Olówu di wàhálà, àwọn ìdílé oyè wọ́ ara wọn relé ẹjọ́
- Ọmọ ìjọ kú sí ìpàgọ́ Bíbélì, pásítọ̀ sìnkú rẹ̀ láì sọ fún ẹbí rẹ̀
- Ìbọn kò ran Tommy, làwọn afurasí ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn bá fi àdá ṣa pa - Óṣojúmikòró
Ẹ ó rántí wí pé awọn oludije fun ipo aarẹ kan ninu ẹgbẹ oselu PDP, ti kede saaju pe awọn ọdọ kan lo da ogoji miliọnu naira jọ lati ra fọọmu idije sipo aarẹ fun awọn.
Lara wọn ni igbákejì Ààrẹ fun ni saa Obasanjo, eyiun Atiku Abubakar ati gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto, Aminu Tambuwal.
Awọn oludije yoku to tun sọ ọrọ naa ni Ààrẹ àná nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin, Bukola Saraki, gómìnà àná ìpínlẹ̀ Anambra Peter Obi àti àwọn mìíràn tíwọ́n ti ra fọ́ọ̀mù láti díje dupò Ààrẹ lọ́dún 2023.
Obasanjọ tó wòye wí pé gbogbo ìpèníjà tó ń bá orílẹ̀ èdè yìí fínra wáyé látọwọ́ àwọn olórí tí kò dára, wa rọ àwọn olùdíje náà láti yé parọ́ mọ fún àwọn ará ìlú wí pé ẹnìkan ló ra fọ́ọ̀mù idije sipo aarẹ fún àwọn.
Ó ní kò sí àwọn ọ̀dọ́ tó le ra fọ́ọ̀mù ogójì mílíọ̀nù náírà gẹ́gẹ́ bí àwọn olùdíje náà ṣe ń sọ.
Bákan náà ló ní ẹni tó bá ra fọ́ọ̀mù, kó jáde síta wí pé òun ra fọ́ọ̀mù, kí wọ́n ye parọ́ wí pé ẹnìkan tàbí àwọn ọ̀dọ́ kan ló ra fọ́ọ̀mù fún àwọn.




















