Olowu Stool: Ọ̀kan nínú ìdílé ọba ní àwọn afọbajẹ dẹ́yẹ sí àwọn lọ̀rọ̀ fi di tilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, LISA
Ìdílé oyè Laara ní Owu, Egba, Abeokuta ti wọ́ idile oye Lumosa ati Otopo pẹlu ileesẹ to wa fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ogun lọ sí ilé ẹjọ́.
Ọrọ naa ko si sẹyin ẹ̀sùn wí pé wọ́n dá iyán mọ̀lẹ́bí àwọn, ìyẹn Laara kéré, lórí ta ni yóò jẹ ọba Olowu.
Iwe ipẹjọ naa, ti asaaju agbẹjọro fun idile naa Adebayo Ogungbemi fọwọsi, lo ti tẹ BBC Yoruba lọwọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Portable Zazzu pàdánù eré tó yẹ kó lọ ṣe ní Canada, ìdí rèé
- Adájọ́ gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹ̀bẹ̀ Rahmon Adedoyin tó ní òun kò ní ẹjọ́ láti jẹ́
- Aráàlú bínú tán l‘Okeho, wọ́n ti iléeṣẹ́ amúnáwá pa torí ségesège iná ọba
- Akẹ́kọ̀ọ́ kan kú mẹ́ẹ̀dógún fara pa nígbà tí ọkọ̀ iléẹ̀kọ́ wọ́n gbiná l‘Ondo
- Ìyá kan rí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún he nítorí ọrọ̀ ọmọ
- Iléèṣẹ́ aṣojú America bẹ̀rẹ ètò físà fún àwọn ọmọ Naijiria láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
- Ìbọn kò ran Tommy, làwọn afurasí ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn bá fi àdá ṣa pa - Óṣojúmikòró
Iwaju ileẹjọ giga tijọba ipinlẹ Ogun si ni wọn gbe ẹjọ naa lọ, ti iwe ipẹjọ naa si se afihan pe ọjọ Kẹtadinlogun osu kẹta ọdun 2022 ni wọn fi iwe ipẹjọ naa sita.
Ki lo wa ninu iwe ipẹjọ naa:
Iwe ipẹjọ naa lo n fẹ ki olujẹjọ kẹta, tii se ileesẹ to wa fun ọrọ oye jijẹ mase lọwọ ninu ohunkohun to nii se pẹlu yiyan tabi kikede ẹni ti yoo jẹ ọba Olowu lai ma jẹ ki awọn olupẹjọ mọ nipa rẹ, titi ti ile jọ yoo fi gbe idajọ rẹ kalẹ lori ọrọ naa.
Bakan naa ni idile Laara naa n fẹ ki olujẹjọ kẹta yii mase tẹwọgba tabi se ipinnu kankan nidi mimu ẹni ti yoo jẹ ọba Olowu lai fi gbogbo idile ọba Otileta sinu rẹ, ninu eyi ti idile Laara wa.

Oríṣun àwòrán, Barr Adebayo Ogungbemi
Awọn afọbajẹ Owu dẹyẹ si wa la se pe ẹjọ - Idile Otileta
Nígbà tó ń gba ẹnu mọ̀lẹ́bí naa sọ̀rọ̀, Ọmọọba Adeyinka Abolade ní àwọn afọbajẹ dẹ́yẹ sí mọ̀lẹ́bí Laara tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí ìdílé oyè Otileta, nínú ètò yíyan ẹni tí yóò gbadé gẹ́gẹ́ bí Olowu èyí tí ìdílé náà ṣe.
Ọmọọba Abolade ni àwọn ti fi ẹ̀dà ripe ipẹjọ naa ráńṣẹ́ sí Balogun Owu, Olóyè Olusegun Obasanjo, Kọmíṣọ́nà fọ́rọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ àti oyè jíjẹ ìpínlẹ̀ Ogun, ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Abeokuta àti gbogbo ìgbìmọ̀ lápapọ̀.
Ó ní àwọn ṣe èyí láti fi fi ẹ̀hónú àwọn hàn lórí bí wọ́n ṣe yọ mọ̀lẹ́bí àwọn nínú ọ̀rọ̀ oyè náà.
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sùn to fi kan awọn afọbajẹ, mọ̀lẹ́bí Laara fẹ̀sùn kàn pé ilé oyè náà ti fi orúkọ márùn-ún ráńṣẹ́ sí àwọn afọbajẹ ṣùgbọ́n tí wọ́n kọ̀ láti mú ọmọ oyè kankan láti inú mọ̀lẹ́bí náà.
Bákan náà ni wọ́n ní pàtàkì mọ̀lẹ́bí Laara sí ilé oyè Otileta kò kéré rárá, fún ìdí èyí àwọn kò ní gbà kí wọ́n yan àwọn jẹ.
Wọ́n ní kí àláfíà lè jọba àti pé kí ìwà ojú ṣàájú le tan nílẹ̀, kí awọn afọbajẹ náà ṣe ìdádúró ṣíṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún àwọn ọmọ oyè tí wọ́n ń ṣe é fún lọ́wọ́ dúró láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún.
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ní àwọn mọ̀lẹ́bí tó gbé ìdílé oyè Otileta ró ni Matemilola, Owookade, Lumosa àti Aderinoye, fún ìdí èyí kò yẹ kí àwọn àgbààgbà ilé ó kọ́ iyán mọ̀lẹ́bí kankan kéré lórí ètò oyè jíjẹ náà.


















