Abeokuta Sagamu cult clash: Oúnjẹ ni Tommy lọ rà fún olólùfẹ́ rẹ̀ táwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn fi pa á

Oríṣun àwòrán, others
Ọkan awọn araalu Abeokuta ati Sagamu n'ipinlẹ Ogun ko ti i balẹ rara, pẹlu bi awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe n fi agba han ara wọn, ti wọn si n pa ara wọn nipakupa kaakiri igboro.
Ilu Abẹokuta to jẹ olu ilu ipinlẹ naa la gbọ pe wahala ọhun ti bẹrẹ, eyi to mu ki awọn eeyan ma le sun oorun asundọkan mọ.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ BBC lọwọ, agbegbe Ẹlẹga ni wọn ti kọkọ pa ọkan lara awọn afurasi naa ti wọn pe orukọ rẹ ni 'Scatter', ẹni ti a gbọ pe ṣe ni wọn ge ọwọ rẹ mejeeji ati ẹya ara rẹ lọ ni kete ti wọn ṣa a pa, ni bi ọsẹ mẹta sẹyin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Adájọ́ gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹ̀bẹ̀ Rahmon Adedoyin tó ní òun kò ní ẹjọ́ láti jẹ́
- Portable Zazzu pàdánù eré tó yẹ kó lọ ṣe ní Canada, ìdí rèé
- Ẹ wo orúkọ àti ojú àwọn èèkànlú tó forí sọta ìkọlù rélùwéè àti ipò tí wọn dì mú
- Aráàlú bínú tán l‘Okeho, wọ́n ti iléeṣẹ́ amúnáwá pa torí ségesège iná ọba
- Kemi Afolabi ti nílò ìtọ́jú pàjáwìrì, a ń gbe lọ sókè òkun - Yomi Fabiyi bú sẹ́kún
- À ń wá láti Ibadan, wá jí ọ̀pọ̀ ọmọ gbé l‘Eko fún ètùtù ọla - Afurasi ajọmọgbe
- Wo bí òògùn lílò àtàwọn nǹkan mìí ṣe le mú kí nkan oṣù obìnrin dáwọ́ dúró láìpé ọjọ́
Ko pẹ si akoko yii la tun gbọ pe wọn lọ dena de ẹlomiran ti wọn pe orukọ tiẹ ni 'School Boy' sile igbafẹ kan ni Aṣero, nilu Abẹokuta.
Bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi iye eeyan to ti ku mulẹ, iroyin sọ pe ko din ni eeyan mẹẹdogun.
Yatọ si Aṣero ati Kugba ti wọn ti pa awọn meji akọkọ, awọn agbegbe bi i Ikereku, Panṣẹkẹ, Adigbẹ, Oke Ijẹun, Oluwo ati Isalẹ Abẹtu, laarin ilu Abẹokuta ni wọn ti pa awọn eeyan yooku.
Ọjọbọ ọsẹ to kọja ni wahala naa fẹju si i, lẹyin ti iroyin jade pe wọn ti pa ọkan lara awọn agba laaarin wọn, ẹni ti wọn pe orukọ rẹ ni Tommy si agbegbe Panṣẹkẹ.
Kinni awọn araalu n sọ lori iṣẹlẹ yii nilu Abeokuta?

Oríṣun àwòrán, others
Gẹgẹ bi ọrọ ti awọn eeyan ba wa sọ nipa iṣẹlẹ yii, lara awọn to mọ Tommy ti wọn pa yii sọ pe eeyan to gbafẹ gidi ni, to si gbajumọ daadaa lagbegbe Oluwo l'Abẹokuta.
Wọn sọ pe ile igbafẹ kan ni Tommy wa pẹlu ọkan lara awọn ololufẹ rẹ, nitosi Oluwo lọjọ t'iṣẹlẹ naa waye.
Tommy jade kuro ninu otẹẹli toun pẹlu ololufẹ rẹ to wa pẹlu rẹ, erongba wọn si ni lati lọ ra ounjẹ fun ololufẹ rẹ naa.
Wọn ni bo ṣe jade kuro nibẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun alatako rẹ ti tẹle e lẹyin lai mọ pe wọn n ṣọ oun lati pa.
Nibi to ti n ra ounjẹ lọwọ awọn to n ta ounjẹ lẹgbẹẹ opopona ni agbegbe Panseke, ni wọn ti yinbọn fun un, ṣugbọn ti ibọn naa ko ran an.
Igba ti wọn lo maa bọju wẹyin lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ, awọn mẹta ti dirọ mọ ọn, ti wọn si bẹrẹ si i ṣa a ladaa.
Awọn ti iṣẹlẹ yii ṣoju wọn ko le duro lati woran, koda ti wọn sọ pe laaarin iṣẹju aaya lawọn ọlọkada atawọn ero to wa ni ikorita ti iṣẹlẹ yii ti waye ti juba ehoro, ti gbogbo agbegbe ọhun si pa lọọlọ.
Ninu awọn to wa nibẹ la gbọ pe wọn ranṣẹ sawọn ọlọpaa lati wa a doola ẹmi awọn eeyan, ṣugbọn to ṣeni laaanu wi pe Tommy ti ku patapata ki wọn to debẹ.
BBC Yoruba tiẹ gbọ pe ṣe lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye yii duro titi t'ẹmi fi bọ lara Tommy, toun jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ lalẹ ọjọ naa, ko to di pe wọn ba ẹsẹ wọn sọrọ.
Wọn loun lo wa nidi bi wọn ṣe pa awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun alatako rẹ, bo tilẹ jẹ pe a ko le fidi rẹ mulẹ lakoko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
Iroyin iku Tommy tun bi wahala miran:
Bi iroyin iku Tommy ṣe jade sita la gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn jẹ ti Ẹiyẹ yii, eyi ti Tommy jẹ ọkan lara awọn olori wọn ṣe jade sita la gbọ pe awọn eeyan naa tun gboro mọ ara wọn lọwọ, ti wọn si bẹrẹ sii f'iku wa ara wọn kaakiri.
Eyi ni wọn lo jẹ k'awọn tiluu Ṣagamu naa dide ogun sira wọn, ti a si gbọ pe awọn ti ko din ni mẹjọ ni wọn pa l'ọjọ Aje si ọjọ Iṣẹgun, gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ.
Ninu ahesọ to tun tẹ wa lọwọ jẹ o di mimọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ti leri wi pe eeyan ti ko din ni mejilelọgọrun-un ni wọn fẹẹ mu balẹ, ko to di pe wahala naa dopin.
Kin ni ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọ?
DSP Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbenusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọ pe awọn ti ko din ni mejidinlogun lọwọ ti tẹ lori rogbodiyan awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii.
O ni lakoko ti awọn wa yii, awọn ti tẹsẹ bọ ṣokoto kan naa pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ati janduku ti wọn n fojoojumọ fa wahala, nitori pe lara awọn tọwọ ti tẹ ti n jẹwọ, ti wọn si ti n ran wọn lọwọ lori ọna ti wọn gbe mu awọn yooku wọn.
Oyeyẹmi tẹsiwaju pe eyi t tun ṣe pataki ni pe awọn yoo bẹrẹ sii lọ fọwọ ofin mu awọn lanlọọdu ti wọn n gba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa sile lati maa gbe, to si ti di dandan lati foju wọn ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii.
Gomina Abiọdun naa sọrọ
Bakan naa ni Gomina Dapọ Abiọdun t'ipinlẹ Ogun ti sọ pe gbogbo ohun to ba gba ni k'awọn agbofinro fun un lati mu awọn ọmọkọmọ to n da omi alaafia ipinlẹ Ogun ru.
O ni ijọba oun wa lẹyin wọn lori iṣẹ ti wọn ba n ṣe láti fi oju awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa hàn, nitori ijọba oun lodi si iwa jagidijagan bo ti wu ko kere to.
Nigba to n fi aidunnu rẹ han si iṣẹlẹ awọn ẹlẹgbẹ okunkun to gba ẹmi awọn kan to si sọ awọn mi-in di alaabọ ara yii, Gomina Abiọdun rọ awọn olugbee Ṣagamu ti wọn fẹran alaafia, pe ki wọn sowọ pọ pelu awọn agbofinro, ki wọn le jọ gbogun ti awọn ẹlẹgbẹ okunkun atawọn ọdaran mi-in lawujọ wọn.
Awọn araalu k'ọwọ ọmọ wọn aṣọ
Ni bayii, pupọ awọn to n gbe ti wọn si n taja l'awọn agbegbe bi i Panṣẹkẹ, Oluwo, Adigbe, Iyana-Oloke niluu Abẹokuta ni wọn ki i di agogo mẹjọ alẹ nita mọ nitori ibẹrubojo ki ọwọ agbofinro ma tẹ wọn.
BBC YORUBA gbọ pe ojoojumọ, paapaa alaalẹ ni awọn agbofinro n kaakiri lati mu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ati janduku ti wọn da wahala silẹ kaakiri.
Bakan naa ni nkan ṣe ri ni awọn agbegbe bii Ajegunle, Sabo ati awọn miran niluu Sagamu.



















