Kemi Afolabi: Yomi Fabiyi ní òun máa ń pa omijé mọ́ra ní, tí òun bà wà lọ́dọ̀ aláìsàn náà àti ọmọ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, realyomifabiyi/Instagram
Bi ọpọ eeyan se n tara poro lori aisan to n se gbajumọ osere tiata lobinrin, Kemi Afolabi, lo ti doju ọgbagade bayii.
Awọn eeyan naa, to fi mọ awọn akẹẹgbẹ rẹ lagbo tiata si lo ti n sare sọtun ati sosi lati doola ẹmi osere tiata naa, ẹni to kede laipẹ yii pe oun ni aisan Lupus, to n ro ni leegun.
Bẹẹ ba gbagbe, a ti mu iroyin wa fun yin saaju nipa awọn osere tiata kan, ti wọn jẹ akẹẹgbẹ Kemi Afolabi, to n ba seto ikowojọ fun itọju rẹ.
- Wo àwọn nǹkan tó le fa lupus - àìsàn tó ń bá Kemi Afolabi fínra
- Dókítà ní ọdún márùn-ún ló kù fún mi láyé, mo sì ti lò lára rẹ̀ - Òṣèré Kemi Afolabi
- Mo ti ra ilẹ̀ ìsìnkú mi ní 'Ebony Vault' ṣùgbọ́n....
- Wo àwọn òṣèré tíátà tó ti fún Kemi Afolabi lẹ́bùn àtàwọn tó ń kíi lẹ́yìn tó kéde àìsàn rẹ̀
- Òṣèré tíátà, Kemi Afolabi dùbúlẹ̀ àìsàn ní ìlú Mecca
- Wo ọmọ Yorùbá mẹ́ta àti gbajúmọ̀ míì tó ní Lupus, àrùn tó n bá Kemi Afolabi fínra
- Ẹ gbà mi o, àwọn oníjìbìtì ayélujára ti ń bèèrè ìrànwọ́ lórúkọ́ mi - Kemi Afolabi lọgun
- Ọ̀rọ̀ tí Kemi Afolabi sọ síta lẹ́yìn táwọn kan ráńṣẹ́ síi torí ìtọ́jú àìsàn Lupus tó ní
- Lórí ìdigunjalè sí Kemi Afolabi, ohun tí òṣèrè náà sọ fáwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ rèé
- Òṣèré tíátà, Kemi Afolabi fi ohùn ìdúpẹ́ ránṣẹ́ láti Meccah fún àdúrà ọmọ Nàíjíríà
Kemi Afolabi ti nilo itọju pajawiri bayii:
Nibayi, gbajumọ osere tiata miran, Yomi Fabiyi ti kede sita lọjọ Aje wipe itọju osere tiata naa ti la kiamọsa lọ.
Fabiyi, ẹni to gbe fọnran fidio kan soju opo Instagram rẹ kede pe osere tiata to n saisan naa lawọn fẹ gbe lọ soke okun ni osu to n bọ.
O ni lootọ ni awọn ọrẹ ati akẹẹgbẹ Kemi Afolabi ti se iwọn ti wọn le se amọ ko ba le rọrun fun osere naa lati gba itọju to yẹ, eyi ti yoo fun ni itura, o si nilo iranlọwọ si.
"Ọpọlọpọ owo la nilo, a ko le da se. Gbogbo ẹyin ti Ọlọrun ran lọwọ, ẹ dakun, ẹ kan si wa.
Wọn ti gba wa nimọran pe ka tun lọ fun itọju ipele keji loke okun, ko le maa sakoso aisan naa nirọrun."
Yomi Fabiyi ni pẹlu iranlọwọ araalu, ẹmi Kemi Afolabi si le gun si.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ọmọ ọdun mọkanla pere ni ọmọ Kemi Afolabi, o nilo ilera pipe fun itọju ọmọ naa:
Yomi Fabiyi wa tẹsiwaju pe osere tiata to n saisan naa ni ọmọbinrin, ọmọ ọdun mọkanla, o si nilo lati se akoso aisan naa fi tọju ọmọ ọhun.
"Akoko ti ọmọ naa nilo itọju lati ọdọ iya rẹ ree, yoo lọ sile iwe ni, se ayẹyẹ ikẹkọjade, yoo se igbeyawo ni, gbogbo eyi ni ọmọ naa nilo iya rẹ fun.
Mo maa n pa ẹkun mọra ni lasiko ti mo ba wa niwaju Kemi, ti mo n wo loju, amọ omi maa n bọ̀ọ loju mi nipa ohun to n la kọja.
Koda, o nira fun mi lati wo oju ọmọ rẹ, ẹ dakun, ẹ se iranwọ fun Kemi Afolabi."
Yomi Fabiyi wa n rawọ ẹbẹ sawọn ẹlẹyinju aanu ọmọ ilẹ yii, lati ran osere tiata naa lọwọ, ko le lọ gba itọju to yẹ loke okun.

















