Kemi Afolabi fi ọ̀rọ̀ ráńṣẹ́ sí àwọn akẹ́gbẹ́ rẹ̀ kan lẹ́yìn tí adigunjalè kọ lu ú

Kemi Afolabi

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Kemi Afolabi
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Kemi Afolabi dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ fún àtìlẹyìn wọn nígbà tí àwọn adigunjalè ṣe àkọlù si

Gbajúgbajà òṣerébìnrin Kemi Afolabi ti fi ẹ̀mí ìmòore hàn sí àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ fún àtìlẹyìn tí wọ́n ṣe fún un nígbà tí àwọn adingunjalè ṣe àkọlù sí i.

Ẹ ó rántí pé lọ́jọ́ karùn-ún, oṣù kìíní, ọdún 2022 ni Kemi Afolabi fi si ori ẹ̀rọ Instagram pé àwọn adingunjalè ṣe àkọlù sí òun ní òpópónà Arepo nínú súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀.

Bákan náà ló fi ojú ọgbẹ́ ibi tí àwọn jàǹdùkú ọ̀hún tí ṣá a ní àdá lede, to si ni wọ́n tún jí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti àwọn ohun ìní rẹ̀ mìíràn gbé lọ.

Ẹ̀wẹ̀, ní òwúrọ̀ yìí ni Kemi Afolabi lórí ẹ̀rọ Instagram rẹ̀ n dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn akẹgbẹ̀ rẹ̀ fún àbẹ̀wò àti àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n fún un nígbà ìṣòro náà.

Àkọlé fídíò, Èmi ni mo yọ "wipe" fi nu omi ẹkún to ti gbẹ́ àti ikun imú nímú òkú ọmọ tí wọ́n gbé lé mi lọ́wọ́ - Ìyá Ojo Emmanuel

"Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún gbogbo ohun tí ẹ ṣe, ẹ kò wá sí ilé mi lásán, owó àti àwọn ẹ̀bùn tí ẹ fún mi pọ̀ púpọ̀ jù".

"Ẹ seun púpọ̀ ẹ̀yin ènìyàn mi, mi ò le dá ọpẹ́ náà tán, Ọlọ́hun yóò bù kún àpò yín, ẹ kò ní rí irú rẹ̀".

Ohun ti o fi si ori Instagram rẹ ree