Nigeria vs Sudan: Super Eagles ń lépa àti gbo ewúro sójú Sudan fún ìpele tó kàn ní AFCON 2021

Awọn agbabọọlu Super eagles n ṣe ajọyọ goolu wọn

Oríṣun àwòrán, Super eagles

Ma binu, fọnran ti o n lò ko le ṣiṣẹ fun un

Ikọ agbabọọlu Super Eagles Naijiria ko ṣere rara ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu orilẹ-ede Sudan to waye ni papa iṣire Stade Roumdé Adijia to wa nilu Garoua lorilẹede Cameroun.

Wọn ko ti i lo to iṣẹju mẹwaa lori papa, ti Samuel Chukwueze fi kọkọ gba bọọlu kan sinu awọn Sudan.

Ka to o tun ṣẹju pẹ́, bọọlu miran lati ọdọ Awoniyi tun ti yí sinu ile Sudan, eyi to mu ki ifẹsẹwọnsẹ naa jẹ ami ayo meji si odo ni abala akọkọ.

A fi bi ẹni pe orilẹ-ede Sudan sin wọn wa sori papa ni ọrọ ri nigba ti abala keji idije naa tun bẹrẹ.

Laarin iṣẹju kan ti wọn wọ ori papa ni ọmọ orilẹ-ede Naijiria, Moses Simon tun ju goolu kan sinu awọn Sudan.

Eyi to mu ki o di ami ayo mẹta si odo.

Awọn agbabọọlu Naijiria ti kọkọ lu ikọ Pharaohs ti orilẹede Egypt lọjọ Iṣẹgun to kọja.

Orilẹede Sudan jẹ ọkan lara awọn ikọ agbabọọlu to ti pẹ julọ ni ilẹ Afirika.

Sudan jẹ ọkan lara awọn orilẹede mẹta to kopa ni idije ife ẹyẹ bọọlu afẹsẹgba ilẹ adulawọ akọkọ, pẹlu Egypt ati Ethipia lọdun 1957.

Ọdun 1970 ni Sudan gba ife ẹyẹ naa nigba to gbalejo idije ọhun.

Papa iṣire Roumdjé Adjia nilu Garoua

Oríṣun àwòrán, cafonline

Orilẹede Naijiria lo n le tente loke ipin D pẹlu ami mẹta lẹyin ti Sudan ati Guinea Bissau ta ọmi olodo ti wọn si ni ami kọọkan.

Bi Sudan ba lee bori ifẹsẹwọnsẹ naa, yoo mu wọn duro digbi lati kogoja fun ipele to kan.

Amọṣa bi o ba jẹ Super Eagles Naijiria lo ba bori, ipele ẹlẹni mẹrindinlogun to kan di dandan fun wọn niyẹn.

Awọn odu ẹlẹsẹ ayo ti aye yoo maa fẹ ri lasiko ifẹsẹwọnsẹnaa

Kelechi Iheanacho ati Moses Simon- Nigeria

Iheanacho ati Salah koju ara wọn

Oríṣun àwòrán, cafonline

Bi o tilẹ jẹ pe Iheanacho lo gba goolu wọle si awọn orilẹede Egypt ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn akọkọ to si gba ami ẹyẹ agbabọlu to pegede julọ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, MVP, amọṣa Moses Simon lo mu ọpọ awọn oluworan bọọlu lọkan ju pẹlu ipa ribiribi to ko ni ifẹsẹwọnsẹ naa.

Àkọlé fídíò, BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

Ali Abu Ashren ati Yasin Hamed - Sudan

Agbabọọlu Sudan ati Guinea-Bissau

Oríṣun àwòrán, cafonline

Abu Ashren ni goli amule fun orilẹede Sudan, O si mu pẹnariti kan ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Guinea-Bissau nibi to ti gba ami ẹyẹ agbabọlu to pegede julọ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, MVP.

Oju rẹ lọpọ yoo tun maa wo lasiko ifẹsẹwọnsẹ wọn.

Yasin Hamed naa wa lara awọn agbabọọlu Sudan to n gba bọọlu jẹun nilẹ Yuroopu. Atamatase ti wọn yoo si maa wo oju rẹ niyi.

Ohun ti awọn akọnimọọgba ikọ mejeeji n sọ

Augustine Eguavoen

Oríṣun àwòrán, cafonline

Akọnimọọgba orilẹede Naijiria, Augustine Eguavoen ni oun ko ro pe ifẹsẹwọnsẹ naa yoo rọrun bi awọn eeyan kan ṣe n ro.

"Gbogbo wa la mọ pataki bibori ifẹsẹwọnsẹ to kan yii. A mọ pe ko ni rọgbọ rara, mo si lero pe bi a ba tete yi ero yii pada ni yoo dara fun gbogbo wa. Gẹgẹ bi ana, orilẹede Cameroun yege, wọn bori lati wọ ipele oloju mẹrindinlogun.

"Awa naa yoo gbiyanju lati ṣe bẹẹ pẹlu. Ko lee rọrun gẹgẹ bi mo ṣe sọ, ṣugbọn afojusun wa niyi."

Burhan Tia

Oríṣun àwòrán, cafonline

Amọṣa ni tirẹ, akọnimọọgba orilẹede Sudan Burhan Tia ṣalaye pe awọn mọ pe Naijiria kii ṣe ẹran rirọ, ṣugbọn awọn ko ni fi eyi ṣe o, awọn yoo ṣe ẹtọ gbogbo to ba yẹ gẹgẹ bi ikọ to fẹ gbẹyẹ mọ Naijiria lọwọ.

"Lootọ ni pe a ṣe awọn aṣiṣe kan ninu ifẹsẹwọnsẹ wa pẹlu Guinea-Bissau, ṣugbọn a lee ṣe ohun gbogbo to ba tọ.

"A mọ pe ikọ to gbayi ni Naijiria, wọn ma maa lepa lati bori ni. Ikọ nla ni ṣugbọn olukuluku lo ni agbara rẹ."