Olubadan throne: Ìdí tí Lekan Balogun ní àwọn ṣetán láti gbé adé ọba kalẹ̀ n'Ibadan

Oríṣun àwòrán, Insideoyo
Osi Olubadan ilẹ Ibadan, Oloye Agba Rashidi Ladoja sọ pe opin ti de ba gbogbo rogbodiyan to n waye lori ẹni ti yoo di Olubadan tuntun.
Ọjọ Satide ni Ladoja sọ ọrọ yii fun awọn akọroyin lẹyin ipade kan ti awọn ọmọ igbimọ Olubadan sẹ pẹlu gomina Seyi Makinde nile ijọba to wa nilu Ibadan.
Oloye Ladoja sọ pe awọn ti fọwọ si yiyan Otun Olubadan, Oloye lekan Balogun gẹgẹ bi Olubadan tuntun.
Bakan lo ṣalaye pe awọn oloye agba nilẹ Ibadan ti yanju ede aiyede to n waye laarin wọn.
Ṣaaju ni ikunsinu ti n waye lori pe Oloye Lekan Balogun ko nii le jẹ Olubadan tuntun, nitori pe o wa lara awọn oloye ti gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo, Abiola ajimobi fi jẹ ọba nilu Ibadan.
Ọjọ Ẹti si ni awọn ọba naa kede pe awọn ti gba lati pada si ipo oloye ti awọn wa tẹlẹ.
Eyi waye lẹyin ti Gomina Makinde sọ pe ohun nikan ni ọna abayọ si yiyan Oloye Balogun gẹgẹ bi Olubadan tuntun.
A ò jẹ́ Ọba mọ́ o! A ṣetán láti padà sí ipò Olóyè tí a wà tẹ́lẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Olubadan - Lekan Balogun
Ọtun Olubadan to waja Sẹnetọ Lekan Balogun ti sọ pe oun atawọn ẹgbẹ oun ti wọn gbega si ipo Ọba laye ijọba gomina tẹlẹ, oloogbe Abiola Ajimobi yoo pada si ipo ti wọn wa tẹlẹ gẹgẹ bii.
Otun Olubadan naa, ti Ade Olubadan kan lo sọ ọrọ ọhun ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Punch.
Ṣaaju ni Makinde ti kọkọ ni ki awọn Oloye naa pada si ipo ti wọn wa tẹlẹ, ki wọn tun pada si bi eto ifinijoye wọn ṣe wa tẹlẹ lọna ati yanju rogbodiyan to n waye lori ẹni ti ade Olubadan kan.

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde
- Ìdìbò 2023: Àwọn ìpèníjà tí Bola Tinubu yóò kojú nínú ìrìnàjò rẹ̀ nìyí
- Háà, nǹkan ṣe mí! Ikú pa ọ̀kan lára àwọn aláànú mi - Yinka Ayefele
- Bí EFCC ṣe mú ayédèrú ọ̀gágun sọ́jà Bolarinwa tó tún ní ẹ̀sùn jìbìtì owó N270m
- Ọkùnrin tó gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ìya rẹ̀ láti fi àbúrò rẹ̀ ṣẹ́ṣó kó sí gbaga Ọlọ́pàá
- Wo àwọn èèkàn mẹ́rin tí Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pàdánù láàárín oṣù kan
- O.Y.O ni Tinubu wa o, a kò ní ṣ'àtìlẹ̀yìn fún un ní 2023 àyàfi ... - Afenifere, Ilana Omo Oodua
- 'Mo mọ̀ pé ọmọ mi tí wọ́n ló pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ n mu igbó, ó sì ní àìsàn ọpọlọ'
- Bí Otunba Adebayo Alao Akala ṣe kú rèé, àti ibi tó dákẹ́ sí gangan - Amúgbálẹ́gbẹ́ Alao Akala
- Wo owó gọbọi tí Nàíjíríà àti orilẹ̀èdè míì ní àgbáyé pàdánù torí wọn ti ojú òpó ayélujára
- A tí ṣé tań láti díje fuń ipò ààre ní ọdún 2023
Balogun ni "Imọran gomina Makinde tẹ wa lọrun nitori oun naa loun dari ijọba ipinlẹ wa... ohunkohun to ba fẹ ni a oo ṣe nitori itẹsiwaju ipinlẹ Oyo ati ilu Ibadan lo jẹ logun."
Ṣaaju ni awuyewuye ti kọkọ n waye lori ẹtọ Otun Olubadan lati gori itẹ naa lẹyin iku Ọba Adetunji.
Asiko ijọba oloogbe Abiola Ajimobi ni wọn gbe awọn oloye naa ga si ipo ọba, ti wọn si bẹrẹ si n de ade, amọ Osi Olubadan, sẹnetọ Rashidi Ladoja , to ti fi igba kan jẹ gomina ipinlẹ naa ri, kọ lati gba igbega ọhun.

Oríṣun àwòrán, @Hrh_Olajuwon
Wayi o, lẹyin iku Ọba Adetunji ni agbẹjọro agba nipinlẹ naa tẹlẹ, Miheal Lana kọ lẹta si gomina Seyi Makinde lati má jẹ ki Otun Olubadan, iyẹn Lekan Balogun, de ipo Olubadan.
Lana sọ ninu lẹta naa pe niwọn igba ti awọn Oloye ọhun ti gba ade gẹgẹ bii Ọba, eyii ti Lekan Balogun jẹ ọkan lara wọn, ko bojumu ki wọn de eeyan kan naa lade lẹẹmeji nitori iru rẹ ko tii ṣẹlẹ ri nilẹ Yoruba.
Amọ awọn oloye naa fesi pada pe igbega ti ijọba fun awọn ko ni ki ẹnikẹni lara awọn má gori itẹ Olubadan to ba jẹ pe ẹni naa oye tọ si.
Wọn gvbe igbesẹ naa nibi ipade kan ti wọn ṣe aafin Olubadan lọjọbọ.
Lara awọn to wa nibi ipade naa ni awọn Oooye ti ọrọ naa kan, to fi mọ awọn Mogaji ka.
Osi-Balogun, Oloye agba Tajudeen Ajibola sọ fu awọn akọroyin lẹyin ipade naa gbogbo oun ti gomina Seyi Makinde ba n fẹ ni awọn yoo ṣe.
Wọn fi kun pe Oloye ṣi ni awọn bo tilẹ jẹ pe wọn ti n dade.
Ẹwẹ, nigba ti Makinde lọ ṣabẹwo si ẹbi Olubadan to waja, o ni ko tii si irufẹ rogbodiyan bayii ri lori iyansipo Olubadan tuntun.
Makinde sọ pe ko si ṣaaju akoko yii nitori ilana ti wa nilẹ tẹlẹ nipa bi wọn ṣe n yan Olubadan mii ti ọkan gbesẹ.
O ni igbega ti ijọba Ajimobi fun awọn oloye ọhun lo da wahala ọhun silẹ.

















