Cubana NDLEA Arrest: NDLEA ní ó jọ pé egbògi olóró ni Cubuna fi tẹ́lẹ̀ ọlà rẹ̀

Ajọ to n gbogun ti lilo egbogi oloro lorilẹ ede Naijiria, NDLEA, lo fi ọrọ wa olowo nni Obi Iyiegbu ti gbogbo aye mọ si Obi Cubana lẹnu wo nipa pe o nii ṣe pẹlu tita egbogi oloro.
Iyiegbu to jẹ alaga agbarijọ ileeṣẹ Cubana ni wọn fọrọ wa lẹnu wo ni olu ileeṣẹ ajọ NDLEA n'ilu Abuja fun bii wakati marun ko too di pe wọn tuu silẹ lati pada wa lọjọ miran.
Oṣiṣẹ ileeṣẹ naa kan ti ko fẹ darukọ ara rẹ sọ fun BBC Yoruba pe awọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA ni wọn ti n tanna wo Cubana ati gbogbo òwò rẹ boya o nii ṣe pẹlu gbigbe egbogi oloro.
- EFCC gbé bàbá olówó Obi Cubana
- Bí EFCC ṣe mú ayédèrú ọ̀gágun sọ́jà Bolarinwa tó tún ní ẹ̀sùn jìbìtì owó N270m
- 'Mo mọ̀ pé ọmọ mi tí wọ́n ló pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ n mu igbó, ó sì ní àìsàn ọpọlọ'
- A ò jẹ́ Ọba mọ́ o! A ṣetán láti padà sí ipò Olóyè tí a wà tẹ́lẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Olubadan - Lekan Balogun
- Háà, nǹkan ṣe mí! Ikú pa ọ̀kan lára àwọn aláànú mi - Yinka Ayefele
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ èèyàn mẹ́rin tó ń jẹ́ ẹran ara èèyàn tí wọ́n tún ń tà ẹ̀yà ara èèyàn
Iroyin to fẹsẹ rinlẹ to tẹ ileeṣẹ BBC News Yoruba lọwọ fihan pe ajọ NDLEA sọ pe awọn oniṣowo egbogi oloro mẹta ti wọn ti ran lẹwọn lorilẹ ede Malaysia, Naijiria ati India sanwo sinu asunwọn banki Cubana.
Gbajumọ naa ni iroyin sọ pe wọn gba kí o lọ ile rẹ, ko le baa mu awọn iwe ti yoo fi ṣọwọ si ajọ NDLEA.
Ni oṣu kọkanla ọdun to kọja, Iyiegbu lo wa ni pampe ajọ EFCC fun ọjọ mẹta lara iwadi sinu awọn ẹsun to jọmọ iṣowo mọku mọku ki wọn to yọnda rẹ lori wipe yoo maa fara han ni waju ajọ naa fun ifọrọwanilenuwo.
A ò jẹ́ Ọba mọ́ o! A ṣetán láti padà sí ipò Olóyè tí a wà tẹ́lẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Olubadan - Lekan Balogun
















