Doctor delivers 'miracle' baby on flight: Bí wọ́n ṣe gbẹ̀bí ọmọ tuntun yìí lójú òfurufú

Ọmọ ti wọn bi ninu baalu

Oríṣun àwòrán, Aisha Khatib

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Dokita ara orilede Canada kan ko lee pa idunu rẹ mọra lẹyin to ṣeranwọ lati gba ẹbi ọmọ tuntun kan leyi to jẹ iyalẹnu lasiko ti wọn n rinrinajo ofurufu lalẹ lọ si orilẹede Uganda.

O ku bii wakati kan ki Dokita Aisha Khatib to jẹ Ọjọgbọn ni Fasiti Toronto gunlẹ si ibi to n lọ ninu kọ baalu Qatar Airways lati Doha lọ si Entebbe nigba tawọn eeyan pariwo fun iranwọ.

Arinrinajo lọ si orilẹede Uganda kan to n pada lọ si ile ni Saudi Arabia lo dede bẹrẹ si ni rọbi lati bi akọbi ọmọ rẹ.

Wiwa si aye ọmọ tuntun jojolo naa fẹ ya a diẹ tori oṣu marunlelọgbọn ni oyun naa ṣi jẹ amọ wọn gbẹbi rẹ to si wa ni ilera pipe. Wọn ti sọ orukọ ọmọ naa ni Miracle Aisha tori Aisha ni oruk Dokita naa to gbẹbi rẹ.

Àkọlé fídíò, Akọ ìbẹ́pẹ ni Yorùbá yóò pè é, ẹ wo bí òṣèré yìí ṣe ń ní ọgbẹ́ ọkàn pé kò tíì r'ọ́mọ bí
Ọmọ ti wọn bi ninu baalu

Oríṣun àwòrán, Aisha Khatib

Dokita Aisha to ti baba jọ ẹni to rẹ latari ọpọlọpọ iṣẹ́ to ti ṣe ni Toronto to ti n bọ nibi to jẹ pe arun Coronavirus gbilẹ gidi gan nibẹ lo rọra n gbadun sisinmi ninu ọkọ baalu lọwọ ti irọbi arabinrin naa bẹrẹ.

Amọ kọ rara nigba ti wọn kede pẹlu gbohungbohun intercom lati bere boya dokita kankan wa ninu ọkọ ofurufu naa.

"Mo rii ti awọn eeyan korajọ yi ẹni naa to n rọbi ka," Dokita Khatib sọ fun BBC. Lasiko yii, o lero pe iṣẹlẹ kan to lagbara gan ni bii ọkàn tí kò ṣiṣẹ́ mọ́.

"Bi mo ṣe wa sunmọ ti mo rii ti obinrin yii dubulẹ lori aga ti ori rẹ wa lapa ẹnu ọna ati ti sẹ koju si oju ferese. Mo si rii ti ọmọ ti n jade bọ!"

Àkọlé fídíò, Èmi ni mo yọ "wipe" fi nu omi ẹkún to ti gbẹ́ àti ikun imú nímú òkú ọmọ tí wọ́n gbé lé mi lọ́wọ́ - Ìyá Ojo Emmanuel

Awọn ero inu ọkọ meji mii lo ṣeranwọ fun Dokita Khatib - ọkan jẹ Nọọ̀sì to maa n wo aisan jẹjẹrẹ, ẹnikeji si jẹ Dokita to n tọju awọn ọmọde latọdọ ẹgbẹ awọn Dokita "Doctors Without Boeders (MSF).

"Ọmọ naa n sọkun gidi gan, lẹyin ayẹwo kiakia tirẹ, o gbe ọmọ naa le Dokita to n tọju awọn ọmọ lọwọ fun ayẹwo finifini.

"Mo wo ọmọ naa mo si rii pe o wa ni ilera pipe, mo wo iya rẹ mo rii pe oun naa wa ni ilera pipe". Eyi ni Dokita Khatib sọ.

O ni lẹyin igba naa loun ki i ku oriire toun si s fun un pe obinrin lanti lanti ni. "Igba yii ni gbogbo awọn to wa ninu ọkọ baalu bẹrẹ si ni patẹwọ ti wọn ṣe ajọyọ".

"Eyi to dara ju ni asiko naa ni pe arabinrin to bimọ pinu lati sọ ọmọ rẹ ni orukọ mi lati fi yẹ mi si".

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ni Dokita naa ba fun ọmọ tuntun naa, Miracle Aisha ni ẹbun ẹgba ọrun oni goolu to wọ sọrun. Lara ẹgba ọrun naa ni wọn fi ede Arabic kọ Aisha si lara.

Igbẹbi inu ọkọ baalu yii waye ni ọjọ karun oṣu Kejila ọdun 2021 ṣugbọn Dokita Khatib ko raye fi awọn aworan ọhun sori ayelujara tori o tun ti bọ sẹnu iṣẹ titọju awọn alaarun Covid-19 ni Toronto.

Ẹwẹ, nigba to tun n pada lọ sile lẹyin iṣẹ eleyii ni ọjọ kejidinlogun oṣu Kejila to wa ninu baalu, ipe mii tun jade fun onimọ iṣegun oyinbo.

"Ọpẹ o, Dokita mii naa wa ninu baalu lọtẹ yii o si ti dahun", Dokita Khatib rẹrin.

"Mo wa sọ pe, tirẹ ni eleyii. Emi ti gbẹbi ọmọ kan lọsẹ meji sẹyin. Too ba nilo mi, mo wa ni ijoko 25A."

Àkọlé fídíò, BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi