Prematured Menopause: Òògùn lílò àti àwọn nkan mìí tó le mú kí nkan oṣù obìnrin dáwọ́ dúró láìpé ọjọ́

Fun ọpọlọpọ obinrin, laarin ọdun marunlelogoji si marundinlọgọta ni nnkan oṣu wọn ma n dawọ duro.
Ṣugbọn, awọn obinrin kan ma n dẹkun ṣiṣe nkan oṣu, ki wọn o to pe ẹni ọdun marunlelogoji.
O le dawọ duro lai si nkan to fa a , o si le dawọ duro nitori awọn oogun kan ni lilo.
- Bó o bá ń gba ẹnu ní ìbálòpọ̀, wo àìsàn tó o lè kó lójú ara rẹ
- 'Èmi àti ìyá mi gbádùn láti máa bá ọkọ mi lájọṣepọ̀, ìdí tí mo fi gbà rèé'
- ''Pásítọ̀ ní kí n gbé ọwọ́ lé ǹkan ọkùnrin ọ̀un, ní ejò dúdú bá jádé...''
- Ṣé irúfẹ́ oúnjẹ tí ò ń jẹ́ lè jẹ́ kí o gbádùn ìbálòpọ̀ rẹ síi?
- Lóòótọ́ ní àṣìṣe wáyé lórí ìṣẹlẹ ìfipábọ́mọdélòpọ̀ nígbà tí mo wà lórí àkóso - Pope Benedict XVI
- Ọkùnrin kan dágbére fáyé lẹ́yìn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀
- Ohun ìṣeré abánilòpọ̀ há sójú ara mi, mo kú tán - Obìnrin ológun kan
Ti o ba jẹ obirnin, ti ọjọ ori rẹ ko ti i to marundinlogoji, amọ ti nkan oṣu rẹ n ṣe segesege, tabi to ti ko wa mọ, o nilo ki o ri dokita rẹ.
Gẹgẹ bi akọsilẹ kan ti ileeṣẹ eto ilera orilẹ-ede United Kingdom fi si ori itakun agbaye rẹ, oriṣiriṣi nkan lo le mu ki nkan oṣu obinrin dawọ duro laipe ọjọ ori to yẹ.
Nnkan oṣu obinrin le dawọ duro laipe ọjọ, lai ni idi kankan.
Gẹgẹ bi akọsilẹ ilera naa ti wi, eyi le ri bẹẹ ti ile ọmọ rẹ ba dẹkun lati ma a pese awọn eroja omoonu 'hormones' kan, paapaa oestrogen.
Nkan to ma n fa eyi ko ti i jẹ mimọ, ṣugbọn fun awọn obinrin kan, lara awọn nkan to le fa a ni wọnyii.
Awọn nkan to ma n mu ki nkan oṣu obinrin dawọ duro laipe ọjọ:
Ti eroja kromosoonu 'Chromosome' ba ni aisan - fun awọn obinrin to ba ni turner syndrome
Aarun to ma n ṣe eroja idaabo bo ara (immune) - ti eroja idaabobo ara ba n kọju ija si tiṣu inu ara
Awọn ajakalẹ aarun bii ikọ ife, aisan iba, ati mumps
Aarun to n ṣe ile ọmọ yii le ràn ninu ìran. Eyi le ri bẹẹ ti mọlẹbi rẹ kan ba dawọ nkan oṣu duro lai pe ọjọ boya nigba ti wọn ko tii pe ọgbọn ọdun.
Itọju aisan jẹjẹrẹ:
Awọn itọju aisan jẹjẹrẹ bi 'radiotherapy ati chemotherapy' le mu ki ile ọmọ da isẹ silẹ.
Eyi le jẹ titi lai, tabi fun igba diẹ.
Bakan naa lo nii ṣe pẹlu ọjọ ori rẹ. Awọn ọdọmọbinrin ti ko ba tii bẹrẹ nnkan oṣu to fi ni jẹjẹrẹ ni okun lati gba awọn itọju jẹjẹrẹ kan ju awọn obinrin to ti dagba lọ.
Iru itọju ti wọn fun ọ - ipa ọtọọtọ ni oriṣiriṣi chemotherapy ma n ni lara ile ọmọ obinrin.
Ibi ti itọju radiotherapy ba doju kọ ninu ara rẹ - o wa ninu ewu lati pe ki nkan oṣu rẹ dawọ duro lai pe ọjọ, ti o ba la itọju radiotherapy kọja ninu ọpọlọ tabi bebe idi.
Iṣẹ abẹ lati yọ ile ọmọ kuro ninu ara
Lara nkan to tun ma n mu ki ile nkan oṣu dawọ duro lai pe ọjọ ni ti obinrin ba ṣe iṣẹ abẹ lati gbe ile ọmọ rẹ jade, fun idi kan tabi omiran.
Awọn apẹẹrẹ nkan oṣu to ba fẹ ẹ dawọ duro lai pe ọjọ:
Apẹẹrẹ gboogi to ma n jẹyọ ti nkan oṣu obinrin ba fẹ ẹ dawọ duro laipe ọjọ, ni pe ko nii wa deede mọ tabi ko dawọ duro lai ni idi kankan bi oyun.
- Awọn obinrin kan le ri awọn apẹẹrẹ bi
- Ara gbigbona ju bo se yẹ lọ
- Iru obinrin naa yoo ma a laagun pupọ ni alẹ
- Oju ara obinrin naa yoo gbẹ́, yoo si ma a ni irora lasiko ibalopọ
- Airi oorun sun
- Aya jija
- Ibalopọ ko nii wu obinrin naa lati ṣe
- Ẹni naa yoo ma gbagbe nkan
Awọn obinrin ti nkan oṣu wọn ba dawọ duro laipe ọjọ tun wa ninu ewu lati ni aarun bi osteoporosis tabi aisan ọka, nitori eroja oestrogen hormones ti ko pọ ninu ara wọn.
Iru itọju wo lo wa fun nkan oṣu to dawọ duro laipe ọjọ?
Itọju gboogi to wa fun awọn obinrion ti nkan oṣu wọn ba dawọ duro laipe ọjọ ni lilo oogun idena ọmọ bibi ti dokita ba kọ fun wọn.
Eyi yoo le fun wọn ni hormones ti wọn n padanu.
O ṣeeṣe ki wọn lo oogun naa titi di ọjọ ori to yẹ ki nkan oṣu dawọ duro (boya bi ọdun mọkanlelaadọta).
Eyi jẹ ọna lati daabo bo wọn lọwọ awọn aarun to le ṣe wọn lẹyin ti nkan oṣu wọn ba dawọ duro.
Ṣugbọn fun awọn to ba ni irufẹ awọn jẹjẹrẹ kan, bii jẹjẹrẹ ọyan, wọn le ma le lo oogun ti yoo fun wọn ni eroja hormones ni agọ ara wọn.


















