Sex: Ọkùnrin kan dágbére fáyé lẹ́yìn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀

olopaa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yorùbá ni òwò tí àdá mọ̀-ọ́n-ṣe ní ń kán àdá léyín, àti pé ikún ń jọ̀gẹ̀dẹ̀ ó ń rèdí kò mọ̀ pé ohun tó dùn a máa pani.

Ọkùnrin kan tí wọn kò tíì mọ orúkọ àti ọ̀nà rẹ̀ kan ti fò ṣánlẹ̀, tó sì gba èkuru lọ́wọ́ ẹbọra ní ilé ìtura kan ní Ada George, ìjọba ìbílẹ̀ Obio-Akpor, ìpínlẹ̀ Rivers lẹ́yìn tó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin kan.

Ìròyìn ní òru ọjọ́rú ní àwọn ọkùnrin àti obìnrin ọ̀hún gba yàrá sí ilé ìtura náà.

Ẹnìkan tí òun náà wà ní ilé ìtura yìí ṣùgbọ́n tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun ṣàlàyé fún àwọn akọ̀ròyìn pé ní nǹkan bí ago méjì òru ni obìnrin yìí lọ gbá ilẹ̀kùn yàrá àlejò mìíràn láti ké gbàǹjerè pé ẹni tí àwọn jọ wọ yàrá ti ṣubú lulẹ̀.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Ó ní alákòso àti ọdẹ ilé itura náà sáré gbe ọkùnrin náà lọ sí ilé ìwòsàn ṣùgbọ́n ẹ̀pa kò bóró mọ́ nígbà tí wọ́n yóò fi dé ibẹ̀.

ibalopo

Oríṣun àwòrán, other

Bákan náà ló ni obìnrin náà sọ fún àwọn pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé ọ̀pá ẹ̀yìn àti ale tí ọkùnrin náà mu lálẹ́ kí wọ́n tó lọ gba yàrá lo ṣe okùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà.

ibalopo

Oríṣun àwòrán, other

Ǹjẹ́ ọlọ́pàá ti gbọ́ sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà?

Nígbà tí àwọn akọròyìn kàn sí agbẹnusọ àjọ ìpínlẹ̀ Rivers, Grace Iringe-Kokom jẹ́rìí sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.Iringe-Kokom ní àwọn ti fi obìnrin náà àti alákòso ilé ìtura sí àhámọ́ àti pé ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.