Ọba Atah ti Ayede Ekiti, Ọba Adeleye Orisagbemi dèrò ilé ìwòsàn l'Ekiti lẹ́yìn tí àwọn agbébọn rọ́jò ìbọn fún un

Oríṣun àwòrán, Ogunmoko
Ọba alade kan ni ipinlẹ Ekiti, Atah ti Ayede Ekiti, Ọba Adeleye Orisagbemi ti dero ile iwosan lẹyin ti awọn agbebọn kan yinbọn lu.
Ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe iṣẹlẹ ọhun waye lọjọ Aiku laarin ilu Isan si Ayede Ekiti ni nnkan bi aago mẹsan alẹ lasiko ti ori ade naa n bọ lati ipada kan.
Awọn oṣoju mi koro sọ pe awọn agbebọn naa gbiyaju lati ji kabiesi naa gbe, amọ wọ dana ibọn fun lẹyin ti igbiyanju wọn fori ṣopọn.
- Àwọn ọmọ Naijiria tó wà ní Ukraine ké gbàjarè lórí ìdẹ́yẹsí tí wọ́n ń kojú lẹ́nu ibodè EU
- Belarus ní ààyè ìpàdé ìpẹ̀tùsááwọ̀ láàrín Ukraine àti Russia ti wà níkàlẹ̀
- Ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de tako ìyanṣẹ́lódì ASUU lónìí
- Ta ni Ajé tí àwọn ọmọ Yorùbá lágbáyé ń ṣọdún rẹ̀ ní Ile Ife lónìí?
- Ọ̀wọ́ngógó epo bẹntiróòlù le tún peléke síi nítorí làásìgbò Russia àti Ukraine
- Mi ò ní ìkùnsínú sí àwọn tó bá mi du àṣíá ìdíje gómìnà ní APC- Oyetola
- Ọmọ Nàìjíríà tó há sí Ukraine kò nílò físà láti wọ Romania àti Poland- Ìjọba Nàìjíríà
- Olùkọ́ dèrò àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tó na akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn án lálubami
Nibo ni ọ̀rọ̀ de duro bayii?
Ọba naa ti n gba itọju nile iwosan bayii kan lasiko ti an ko iroyin yii jọ.
Gbogbo akitiyan lati kan si ori ade naa lo ja si pabop, amọ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu fidi iroyin naa mulẹ fun BBC Yoruba.
Amọ Abutu sọ pe ilu Ijero Ekiti ni Ọba Orisagbemi ti n bọ, tako iroyin to kọkọ sọ pe ilu Isan lo ti n bọ ko to kagbako awọn ẹni ibi naa.
O ni awọn ti bẹrẹ iṣẹ lati ṣawari awọn agbegbọn ọhun, ati pe Oba Orisagbemi ti n gba itọju lọwọ lẹyin ti awọn gbe lọ sile iwosan.
Ikọlu awọn agbebọn si awọn Ọba ilẹ Yoruba
Ti ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu kọkanlan ọdun 2020 ni awọn agbebọn kan ṣekupa Ọba Israele Adewusi, to jẹ Olufon ti ilu Ifon, ni ipinlẹ Ondo.
Nigba to di inu oṣu Kẹfa ọdun 2021, awọn agbebọn ji Eleda ti Eda-Ile Ekiti gbe, iyẹn Ọba Benjami Osho.
Iṣẹlẹ ijinigbe Eleda yii lo waye ni nnkan bi oṣu meji ti awọn agbebọn kan ti kọkọ ji Ọba David Adegboyega, to jẹ Obadu ti Ilemosho gbe, ko to gba itusilẹ lẹyin ọjọ marun un.
















