Russia and Ukraine war: À ń kojú ìdẹ́yẹsí lẹ́nu ibodè EU - àwọn ọmọ Naijiria ké gbàjarè láti Ukraine

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ọmọ bibi ilẹ Afrika to n gbiyanju lati fi orilẹ-ede Ukraine silẹ ti ke gbajare lẹyin idẹyẹsi ti wọn n dojukọ lẹnu ibode ati wọ ilẹ EU.
Ọmọ Naijiria kan to n kẹkọọ nipa imọ iṣẹgun ni fasiti Kharkiv, Ruqqaya, sọ pe oun fẹsẹ rin fun wakati mọkanla lorumọju ki oun to de Medyka-Shehyni, to jẹ ibode Poland amọ wọn ko jẹ ki oun wọle.
O ni "Nigba ti mo de ibi yii, mo ri awọn alawọ dudu ti wọn n sun ni ita gbangba."
- Ẹ̀yin èèyán ẹ gbàmí, Ààrẹ Russia, Vladimir Putin fé pa mí - Sunday Adelaja
- Wo ìgbésẹ̀ tí ìjọba àpapọ̀ gbé lórí àwọn ọmọ Naijiria tó ń sá kúrò ní Ukraine
- Olùkọ́ dèrò àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tó na akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn án lálubami
- Inú ìbẹ̀rùbojo ni a wà báyìí ni Ukraine léyìn tí Russia kógun wọlé - Sunday Adelaja
- Ọmọ ọdún mẹ́tàlá gún ènìyàn pa nítorí owó ìrèké ní ìpínlẹ̀ Borno
Gẹgẹ bii ohun to sọ, wọn ko gba laaye lati wọ orilẹ-ede naa nitori wọn ni awọn ọmọ ilẹ Ukraine ni yoo kọkọ wọle, amọ ko le sọ boya ọmọ orilẹ-ede Poland ni awọn aṣọbode naa tabi ti Ukraine.
O ni oun ri ti wọn faye gba ẹgbẹlẹgbẹ awọn alawọ funfun lati wọle lẹnu ibode naa, ṣugbọn iwọmba perete awọn ọmọ ilẹ Afrika ni wọn jẹ ko wọle.
- Ìjọba Nàìjíríà gbọ́dọ̀ tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ Sunday Igboho, Nnamdi Kanu àti gbogbo àjìjàngbara tí wọ́n fìyà jẹ- Sowore
- Ajínigbé ṣe ìkọlù ní Kaduna akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta fara gbọta, 57 míìràn dàwátí
- Wo ìdí pàtàkì mẹ́ta tí Russia se kọlu Ukraine
- Kílódé tí NATO kò ṣe fẹ́ gbè lẹ́yìn Ukraine?
- Kini Wòlíì rí tó fí yìnbọn lú arábìnrin ẹní ọdún 18 tó sá wọ ilé ìjọsìn rẹ́?
Ruqqaya n gbiyanju lati de Warsaw nibi ti yoo wọ baluu ti yoo gbe pada wa si Naijiria.
Ni ti alawọ dudu miran, Isaac, to de ẹnubode Medyka ni aago mẹrin abọ idaji, o ni awọn aṣọbode sọ fun oun pe awọn ọmọ orilẹ-ede Turkey ni yoo kọkọ wọle, ko to kan awọn ọmọ bibi ilẹ Afrika.
Awọn eeyan miran tun sọ fun BBC pe awọn ti ha si ẹnubode Przemyśl nitori awọn aṣobode ilẹ Ukraine ko gba awọn laye lati kọja.
Timothy to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ akẹkọọ Naijiria ni Lyviv ni ohun ti oju awọn n ri ni awọn ẹnubode naa kii ṣe keremi, ati pe iyawọ wa laarin bi wọn ṣe n ṣe si awọn ọmọ Ukraine ati awọn to jẹ alawọ dudu.
Segun, to jẹ akẹkọọ ni Kyiv ni oun ko le lọ si ẹnubode nitori iwe irinna oun wa lọwọ awọn to ba oun to paali oun de orilẹ-ede naa.
Ẹwẹ, ọọfisi ijọba Naijiria ni Poland ti sọ pe oun ti ko awọn oṣiṣẹ kan lọ si ẹnubode naa lati ṣeranwọ fun awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ rekọja lati Ukraine si Poland.

















