Olùkọ́ dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn tó na akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn án lálubami

Oríṣun àwòrán, @lucienbodo
Awọn ọlọpaa ni Cameroon ti fi ṣikun ofin mu olukọ kan, lẹyin ti fidio bo ṣe na akẹkọọ to jẹ ọmọ ọdun mẹsan an jade lori ayelujara.
Iroyin ni iṣẹlẹ naa waye ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ kan ni Doula, to jẹ ilu ti ọrọ aje rẹ milẹ titi julọ ni Cameroon.
Ogunlọgọ eeyan lo ti pin fidio naa lori ayelujara, eyii to mu ki ọpọ eeyan bu ẹnu atẹ lu iwa ti olukọ naa wu.
- Ẹ̀yin èèyán ẹ gbàmí, Ààrẹ Russia, Vladimir Putin fé pa mí - Sunday Adelaja
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Aiye márùn ún tí wọ́n ti ń wá l'Ogun
- Ọmọ ọdún mẹ́tàlá gún ènìyàn pa nítorí owó ìrèké ní ìpínlẹ̀ Borno
- Ìjọba Nàìjíríà gbọ́dọ̀ tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ Sunday Igboho, Nnamdi Kanu àti gbogbo àjìjàngbara tí wọ́n fìyà jẹ- Sowore
- Ajínigbé ṣe ìkọlù ní Kaduna akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta fara gbọta, 57 míìràn dàwátí
Fidio ọhun ṣafihan akẹkọọ naa ni ihoho, ti awọn okunin meji si di ọwọ ati ẹsẹ rẹ mu.
Lẹyin naa ni olukọ ọhun bẹrẹ si fi rọba na akẹkọọ naa, ko to tun bẹrẹ si n fi pẹtẹpẹtẹ ada na.
Gẹgẹ bii ohun ti oṣojumikoro kan sọ fun awọn akọroyin, ijiya naa ko ṣẹyin bi akẹkọọ ọhun ko ṣe le ṣalaye idi ti ko ṣe yọju sile ẹkọ fun awọn ọjọ diẹ.
Ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.
Ẹwẹ, ijọba Cameroon ti fofin de ki olukọ maa fiya jẹ akẹkọọ amọ awọn ile ẹkọ kan ṣi maa n da seria fun awọn akẹkọọ wọn.
- Wo ìdí pàtàkì mẹ́ta tí Russia se kọlu Ukraine
- Kílódé tí NATO kò ṣe fẹ́ gbè lẹ́yìn Ukraine?
- Kini Wòlíì rí tó fí yìnbọn lú arábìnrin ẹní ọdún 18 tó sá wọ ilé ìjọsìn rẹ́?
- Ìjọba àpapọ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìkọlù Russia sí Ukraine àti ìgbésẹ̀ rẹ̀ lórí àwọn ọmọ Naijiria tó wà níbẹ̀
- Ẹ gbàgbé pé mo lọ gba ìtọ́jú ní London, mo ní ọpọlọ pípé láti tukọ̀ Naijiria - Tinubu













