Suicide attack: Ìlú Konduga Pàdánù ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy
Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Borno ni wi pe ọgọrọ eniyan ti dero ọrun nirọlẹ ọjọ aiku.
Akọroyin kan sọ fun BBC pe eniyan mẹta to gbe ado oloro si ara wọn jẹ ki ado oloro naa ro gbamu lara wọn.
Eyi waye ni iwaju ita gbọngan kan ni ilu Konduga nibi ti awọn ololufẹ ere bọọlu ti maa n woran lori ẹrọ amohumaworan.
Oṣiṣẹ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ naa, usman Kachalla wi fun ile iṣẹ iroyin AFP pe "iye ẹmi to nu ti to ọgbọn ti o si le ni ogoji to fara pa.










