FIFAWWC: Falcons fìdí rẹmi, sùgbòn ọmọ Nàìjíríà gbóríyìn fún wọn

France ati Super Falcons

Oríṣun àwòrán, FIFA.COM

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awon omo Naijiria kan saara si ẹgbẹ agbaboolu obinrin Naijiria, Super Falcons lẹyin ti ikọ France bori wọn ninu idije ife ẹyẹ agbaye awọn obinrin pẹlu ami ayo kan si odo.

Oju opo Twitter mì titi lẹyin ifẹsẹwonse naa pẹlu bi awon ololufẹ ikọ Super Eagles ṣe gboriyin fun ikọ Super Falcons nitori wọn gbiyanju lati se daradara ju ikọ France.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3

Ikọ France ti di olori Group A bayii ninu idije ife ẹyẹ agbaye awọn obinrin, FIFA Women's World Cup lẹyin ti wo-mí-ngba-si-ọ ti adari ifẹṣẹwọnsẹ naa fun Wendie Renard lati gba ni ẹẹmeji.

Super Falcons nilo ọmi ninu ifẹsẹwọnsẹ o kere tanalẹ oni lati tẹsiwaju ninu idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ lorilẹede France.

Nnkan ko ṣẹnu fun ikọ agbabọọlu Naijiria ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti wọn gba lẹyin ti Norway fiya jẹ wọn pẹlu ami ayo mẹta sodo.

Ṣugbọn ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria jẹwọ orukọ wọn gẹgẹ bi aṣaaju ikọ agbabọọlu obinrin lati ilẹ adulawọ lẹyin ti fagba han South Korea pẹlu ami ayo meji ninu ifẹsẹwọnsẹ keji ti wọn gba.

Bo ti lẹ jẹ pe Super Falcons ja kulẹ ninu ifẹsẹwọbnṣẹ wọn pẹlu France, wọn ṣi ni anfani lati wa lara awọn ikọ mẹrindinlogun akọkọ ti wọn si tun le gbe ipo kẹta.

Akọnimọọgba Super Falcons Thomas Dennerby gborinyin fun ikọ obinrin Naijiria naa. O ni akọni ni wọn, o si fi aidunu rẹ han wipe wọn fun France laaye lati gba wo-mí-ngba-si-ọ lẹẹmeji ọtọtọ.

Àwọn oun ti a ti sọ tẹlẹ:

Akọnimọọgba Super Falcons, Thomas Dennerby sọ pe oun nigbagbọ pe Naijiria si le fakọyọ lalẹ oni bi wọn ti ṣe pẹlu South Korea.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

O fikun ọrọ rẹ pe yoo dara julọ ti Naijiria ba le fagba han France, nitori yoo fun wọn ni igboya lati koju ẹnikẹni ni ipele ẹlẹnimẹrindinlogun.

Ami ayo mẹjọ sodo ni France fun Super Falcons ninu ere bọọlu ọlọọrẹsọọrẹ ti wọn jọ gba lọdun 2018.

Ṣe Super Falcons le yi ero Afirika pada lori ere bọọlu awọn obinrin?

Fun awọn agbabọọlu Naijiria, ife ẹyẹ agbaye awọn obinrin kọja ere bọọlu lasan.

Super Falcons ati France

Oríṣun àwòrán, Twitter/NG_Super Falcons

Ikọ Super Falcons nikan lẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Afirika ti ko tii pa ikankan jẹ ninu gbogbo idije ife ẹyẹ agbaye to ti waye lati ọdun 1991 ti idije naa ti bẹrẹ.

Ṣugbọn oniruuru iṣoro lo n koju awọn agbabọọlu obinrin lorilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Éégún tó wà nídí Yoruba Bollywood, Samo Baba f'ojú hàn o!

Ọpọ eeyan ni ko ri ere bọọlu ni Naijiria gẹgẹ ere idaraya to yẹ ki obinrin maa ṣe.

Ẹlẹsẹ ayo fun Naijiria to n gba bọọlu fun ikọ Barcelona, Asisat Oshoala sọ pe bakan naa lọmọ ṣori kaakiri gbogbo ilẹ Afirika.

Àkọlé fídíò, Iba Gani Adams: Bẹ́ẹ gbé màláíkà kan lọ sí Aso Rock, kò lè ṣàṣeyọrí

Oshoola ni awọn agbabọọlu ni Afirika n gbiyanju lati yi ero ọpọ eeyan nilẹ Adulawọ pada pe obinrin ko wa fun ile idana nikan.

Ninu idije ọdun 1999 ni Super Falcons ti rin jina julọ nigba ti wọn de ipele komẹsẹoyọ ẹlẹni mẹjọ.

Iṣẹ pọ fun wọn lati ṣe nigba ti wọn ba koju France lalẹ ọjọ Aje.

Asisat Oshoala ree fun ikọ Barcelona pẹlu Bayern Munich ninu idije Women's Champions League

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Akẹgbẹ Oshoala, Francisca Ordega to n gba bọọlu fun ikọ Shanghai Shengli tiẹ sọ pe Naijiria niṣẹ to pọ lati ṣe lori ero awọn eeyan nipa ere bọọlu obinrin.

Ordega ni mama oun sọ fun oun pe ko si ọkunrin to maa fẹ oun sile niwọn igba t'oun ba tẹsiwaju pẹlu bọọlu gbigba.

Ṣugbọn o ni inu mama oun ti dun bayii nitori oun ti di araba ninu bọọlu gbigba.

Ordega to jẹ ẹni ọdun marundinlọgbọn ti gba bọọlu lorilẹede Russia, Sweden, America, Australia, Spain ati China.

Francisca Ordega

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Francisca Ordega nigba to n gba bọọlu fun ikọ Sydney FC

Ọjọ ẹsan Super Falcons lara France

Ordega ranti bi France ṣe lu Naijiria ni alubami ni bii ọdun sẹyin, nitorinaa, ohun kan ṣoṣo to wa lọkan rẹ ni eṣan.

Ordega ni ''awọn ko bẹru France,'' o ni ami ayo mẹjọ ti France ka lawọn kii ṣe ohun toju ko riri.

O fikun ọrọ rẹ pe Germany ti na Naijiria ni 8-0 ri lọdun 2011 ṣugbọn wọn se e ki wọn to jẹ ẹ nigba tawọn mejeeji pade ninu idije ife ẹyẹ agbaye.

Akẹgbẹ rẹ, Oshoala naa sọ pe ko le sẹeṣe ki France na Naijiria ni 8-0 lọdun 2018, ki wọn tun wa tun wọn na lalẹ ọjọ je.