AFCON 2019: Rohr já Iheanacho àti Semi jùú lẹ̀ lọ Egypt

Ahmed Musa, Mikel Obi ati Kenneth Omeruo

Oríṣun àwòrán, Twitter/NFF

Àkọlé àwòrán, Igbaradi Super Eagles for idije AFCON 2019
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ikọ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles ti mori le ilu Ismaila lorilẹ-ede Egypt fun aṣekagba igbaradi wọn for idije ere bọọlu awọn ọkunrin l'Afirika.

Sugbọn agbabọọlu ẹlẹsẹ ayo, Kelechi Iheanacho ati Ṣemi Ajayi ko ni ba wọn lọ.

Iheanacho ati Ajayi wa lara awọn agbabọọlu mẹẹdọgbọn ti akọnimọọgba Super Eagles, Gernot Rohr kọkọ f'orukọ wọn sita, ṣugbọn o yọ wọn kuro ninu ikọ agbabọọlu ti yoo ṣoju Naijiria lorilẹ-ede Egypt.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Nnkan ko ṣ'ẹnu 're fun Iheanacho ni ikọ agbabọọlu rẹ naa nilẹ Geẹṣi, Leicester City ni saa ere bọọlu to kọja, nitori ọpọ igba lo maa n joko wo'ran ti awọn akẹgbẹ rẹ ba n gba bọọlu.

Igbiyanju rẹ nibi ti ikọ Super Eagles ti n bẹrẹ igbaradi wọn niluu Asaba naa ko tun wu olukọ Super Eagles, Rohr lori, eyi to jẹ ko ja a ju silẹ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ṣemi Ajayi ni tirẹ fakọyọ fun ẹgbẹ agbgabọọlu, Rotherham United nibi to ti n gba bọọlu jẹun nilẹ Gẹẹsi ṣugbọn awọn agbaọjẹ agbabọọlu ti wọn jọ n gba aye kan naa ni ko jẹ ko raye.

Àkọlé fídíò, #Sweetsweetcodeine: Ẹ wo bí ìròyìn BBC nípa oògùn ikọ́ Codeine ṣe ń tún ayé tó ti bàjẹ́ ṣe

Ọmi odo sodo ni Super Eagles ta pẹlu Zimbabwe ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọọrẹsọọrẹ ti wọn jọ gba lọjọ Abamẹta ni papa iṣere Stephen Keshi niluu Asaba.

Kelechi Iheanacho ati Semi Ajayi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Igbaradi Super Eagles for idije AFCON 2019

Naijiria yoo to koju Senegal ninu ere bọọlu ọlọọrẹsọọrẹ miiran lọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹfa lorilẹede Egypt ki idije AFCON 2019 to bẹrẹ.

Naijiria wa ni isọri keji pẹlu Burundi, Madagascar ati Guinea fun idije AFCON 2019.

Àkọlé fídíò, '500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'