Super Falcons: 3-0 ni Norway fi ṣi'de ìyà fún Nàìjíríà

2019 Women's World Cup between Nigeria and Norway.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọbinrin agbabọọlu Naijiria, Osinachi Ohale gan an lo gba bọọlu si inu awọn Naijiria ti ayo naa fi di mẹta si odo.

Orilẹede Norway ti si'de idije erebọọlu awọn abinrin ni agbaye, Women's World Cup pẹlu bi wọn se naa ikọ Super Falcons Naijiria pẹlu ami ayo mẹta si odo.

Guro Reiten ti ikọ Norway lo kọkọ gba bọọlu naa si inu awọn ni isẹju mẹtadinlogun ti ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ, ko to di wi pe Lisa-Marie Utland naa fi ọba le, to fi jẹ ami ayo meji si odo.

Àkọlé fídíò, Ondo: Dejí sun ọmọ méje àtagbalagba meji mọ́lé nítorí pé ó ń bínú

Osinachi Ohale ti ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria naa lo wa bọrọ jẹ patapata, ti o si gba bọọlu wọle si oju ile ara rẹ, eyi to mu ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari si ami ayo mẹta si odo fun ikọ Norway.

2019 Women's World Cup between Nigeria and Norway.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ikọ agbabọọlu Norway to gba Ife Ẹyẹ naa ni ọdun 1995 lo jawe olubori pẹlu bi ko se si gbajugbaja elere bọọlu wọn, Ada Hegerberg ni ifẹsẹwọnsẹ naa.

Àkọlé fídíò, 'Mí ò ya wèrè, mí ò burú, ọ̀nà àtijẹ là ń wá'