Akure-Owo Accident: Ẹ̀mí 18 ṣòfò ní òpópónà ti ọ̀pọ̀ ti ń kú ní ìpínlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, Dominic Edem
Iroyin ibanujẹ kan ni ọjọ Abamẹta wipe awọn eniyan mejidinlogun ti ṣegbe sinu ijamba ọkọ kan ni popona Akure-Owo, Oba Ile ni Ipinlẹ Ondo.
Iroyin fi han wi pe ọkọ ajagbe elepo kan lo ja ti o si fori sọ ọkọ akero kan to n bọ ni iwaju ni nkan bi aago mẹta aabọ oru.
Agbẹnusọ fun iileeṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Ondo Femi Joseph sọ wi pe ni kete ti ọkọ mejeeji fori sọ ara ni ina sọ, ṣugbọn awakọ ọkọ ajagbe naa ti ọmọ onimọto rẹ bẹ silẹ wọn si fẹsẹ fẹ.
Ọlọpaa ni awọn ṣi n wa awakọ naa ati ikeji rẹ to sa lọ
Ilu Eko ni a gbọ pe ọkọ akero naa ti n bọ ti ọkọ ajagbe naa si n bọ lati Ọwọ.
Popona ti gbẹmi ọpọ awọn arinrin ajọ ni ni aarin ọdun meloo kan sẹyin a yii.
Ni oṣu kẹta ọdun 2011, eniyan bi mẹrinlelogun lo ku nigba ti ijamba ọkọ kan ṣẹlẹ ni popona naa. Eniyan meji tun ku loju ọna naa ninu ijamba miiran ni ọdun 2017.









