Ondo police: Ìwádìí ń tẹ̀síwájú lórí ìjínigbé náà

Bisi Ogungbemi
Àkọlé àwòrán, Agbẹ́nusọ́ fún ilé isẹ́ ọlọ́ọ̀pàá ní ìpínlẹ̀ Ondo ní lóòtọ́ ni ìsẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní ọ́ná Ọ̀bà Àkókó àti pé ìjínigbé wọ́pọ̀ lágbèègbè náà.

Ile iṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ti fi idi ẹ mulẹ pe lootọ ni awọn ajinigbe ti ji Alaga Ẹgbe Oselu ADC ni ipinlẹ Ondo, Bisi Ogungbemi ati awọn mẹrin miran lọ.

Awọn mẹrin miran ti awọn ajinigbe naa jigbe lọ ni Oludije sipo sẹnetọ lẹkun idibo ariwa ni ipinlẹ Ondo lẹgbe oṣelu ADC, Jide Ipinsagba, Ọmọọbabinrin Funmilayo Abdulraman to jẹ aṣaju awọn obinrin ni Guusu Ondo, Abẹsinkawọ Alaga, Arakunrin Idowu ati awakọ wọn.

Agbenusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa, Femi Joseph to ba BBC Yoruba sọrọ ni irọlẹ ana ni isẹlẹ naa waye ati wi pe awọn adigunjale ti maa n ṣọṣẹ ni agbegbe Ọba-Akoko to wa lọna Ọwọ si Akungba-Akoko.

Àkọlé fídíò, Ìnú mi kìí dùn nígbà trí mo ń ṣiṣẹ́ ni bánkì tó ìgbà ti mo bẹ̀rẹ̀ mẹkáníìkì

Joseph ni iwadii ti n lọ lọwọ lati ri awọn ajinigbe naa ati lati doola ẹmi awọn ti wọn jigbe naa.