Pius Adesanmi: Ìdílé ọ̀jọ̀gbọ́n tó kú níjàmbá Ethiopian Airlines ló ilé ẹjọ́

Adesanmi
Àkọlé àwòrán, Pius Adesanmi: Awọn ọmọ Nàìjíríà ń ṣelédè lẹ́yìn akọni

Gbogbo ọmọ Naijiria ṣe ìdárò ọjọgbọn Adesanmi

Idile oloogbe Pius Adesanmi, ọjọgbọn ọmọ Naijiria to ku sinu iṣẹlẹ ijamba ọkọ ofurufu Ethiopian Airlines (ET302) to waye ni oṣu kẹta ti gbe ileesẹ to n ṣe ọkọ ofurufu Boeing lọ ile ẹjọ.

Boeing lo ṣe ọkọ ofurufu 737 Max 8 naa to pa eniyan metadinlọgọjọ, ki awọn oluwadii to wa fi han pe, ọkọ naa ni abawọn.

Àkọlé fídíò, BBC Africa Eye: Akọroyin fẹ ìdí àwọn oníṣẹ́ ibi ọmọ ogun síta

Iyawo ati ọmọ oloogbe Adesanmi ni orukọ wọn wa lori iwe ipẹjo ti awọn agbẹjọro lati ileesẹ mẹta - Nomaan Hussain, Floyed Wisner ati Omar Khawaja - fi ranṣẹ si ileeṣẹ Boeing.

Iroyin fi han pe ilu Chicago ni orile-ede Amerika ni wọn ti pe ẹjọ naa.

Àkọlé fídíò, Odebiyi: ìgbà gbogbo ni Bàbá mi ń polówó iṣẹ́ mi fáráyé

Ẹjọ naa da lori pe ileeṣẹ naa ko fi to awọn awakọ ofurufu leti awọn ewu to rọ mọ awọn irinṣẹ tuntun ti wọn fi n rinna ofururu to wa ninu Max 8 naa.

Àkọlé fídíò, Mo ń retí láti ọ̀dọ̀ bàbá mi nígbà tí mo gbọ́ pé ó bá ìjàmbá bàálù lọ

Adesanmi to jẹ ọjọgbọn ni fasiti kan ni orilẹ-ede Canada in rinrin ajọ lọ orilẹ-ede Nairobi lati Addis Ababa nigba ti ọkọ naa ja lulẹ laarin iṣeju mẹfa to gbera.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Pius Adesanmi ní Wole Soyinka ìran yìí - ọmọ Naijiríà