Ọjọ Aje ni wọn saba maa n ṣe õdun yii gẹgẹ bi orukọ oriṣa naa

Àjọ̀dún Ajé gbìnàyá nílùú Ile Ife, Ooni Adeyeye Ogunwusi kó àwọn ọmọ Yorùbá lẹ́yìn ṣọdún ọrọ̀ àti ọlá.
Ni ọjọ Ẹti ni ayẹyẹ iṣide ajọdun isembaye naa waye nibi ti kabuyesi Ọọni ti Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji, ti ṣi i pẹlu apero ọrọ aje ati iṣẹṣe ni ile ife.
- Àwọn ọmọ Naijiria tó wà ní Ukraine ké gbàjarè lórí ìdẹ́yẹsí tí wọ́n ń kojú lẹ́nu ibodè EU
- Olùkọ́ dèrò àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tó na akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn án lálubami
- Ajínigbé ṣe ìkọlù ní Kaduna akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta fara gbọta, 57 míìràn dàwátí
- Wo ìdí pàtàkì mẹ́ta tí Russia se kọlu Ukraine
- Kini Wòlíì rí tó fí yìnbọn lú arábìnrin ẹní ọdún 18 tó sá wọ ilé ìjọsìn rẹ́?
- Ìjọba àpapọ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìkọlù Russia sí Ukraine àti ìgbésẹ̀ rẹ̀ lórí àwọn ọmọ Naijiria tó wà níbẹ̀
- Ẹ gbàgbé pé mo lọ gba ìtọ́jú ní London, mo ní ọpọlọ pípé láti tukọ̀ Naijiria - Tinubu
Kini eto to wa nile fun ọdun Aje 2022 ni Ile Ife?
Agbẹnusọ fun Ọọni, Ọtunba Moses Ọlafare ṣalaye pe iyalaje oodua, Ọmọwe Toyin Kólade ti ṣeto gbogbo lati rii pe eto gbogbo to.
Ni ọjọ Satide ọjọ kẹrindinlọgbọn osu keji ni ajọdun orin Aje waye nibi ti oniruuru orin iṣẹmbaye ati orin faaji gbogbo ti wa nikalẹ fun gbigbo.
Ki ni pataki Ajọ Aje?
Gẹgẹ bi ohun ti aafin Oodua sọ, Oriṣa Aje lo wa ni akoso ọrọ aje, ọrọ, karakata ati ijafafa okoowo gẹgẹ bi Ogun ṣe n ṣakoso irin ti Ọṣun ṣi n ṣakoso omi.
Ọjọ Aje ni wọn saba maa n ṣe õdun yii gẹgẹ bi orukọ oriṣa naa.

Kini ikede Kabiesi Ooni lori odun Aje 2022?
Ninu ọrọ ti Kabiyesi Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi sọ lasiko ajọdun yii lọdun diẹ sẹyin, "Aje jẹ oriṣa to gbajumọ fun ọrọ, ọla ati owo. Gẹgẹ bi ẹ si ti ṣe ri loni, ajọdun yii wa lati sami ipa pataki to ni I ko ninu aye wa, paapaa julọ ọrọ aje fun wa."
Bawo ni aṣekagba ajọde Aje tọdun yii yoo ṣe lọ?
Ipele mẹta ni aṣekagba ọdun Aje tọdun yii yoo ṣe waye.
Akọkọ ni ikọwọrin Aje Olokun ti awọn obinrin Woye Aṣiri lati agbole Ilero, Ọsangangan Obamakin yoo ṣe wa ki Kabiyesi Ọọni Ile Ifẹ laafin Oodua.
Nibe ni eyi ti wọn yoo ti kọwọrin pẹlu Arole Oodua lọ si ojubọ Aje to wa ni ọja iṣẹmbaye Ejigbomekun ti ọpọlọpọ mọ si Ọja Ifẹ bayii.
Lẹyin eyi lawọn obinrin Woye Aṣiri yoo fi ojubọ Aje silẹ lọ si odo Yeyemolu to wa laafin Ọọni fun awọ etutu to ku.
Pabambari ajọdun naa ni ikọwọrin awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ oriṣa Aje gbogbo ti Ọọni yoo ko sodi pẹlu awọn agbagba Ifẹ, awọn ọbalaye kaakiri agbaye ati iyalaje Oodua Ọmọọba Toyin Kọlade















