South Sudan: Ààrẹ àti alátakò rẹ̀ kò jẹ́ kí àláfíà jọba

Awọn obinrin orilẹede South Sudan ti wọn gbe ohun ija lọwọ

Oríṣun àwòrán, AFP

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní bí ara ilé ẹni bá ń jẹ kòkòrò burúkú tí a kò bá sọ fun, kùrùkẹrẹ rẹ̀ kò ní jẹ́ kí ènìyàn sùn lóru.

Àwọn orílẹ̀ èdè tó mú ilé ti South Sudan ti ní orílẹ̀ èdè náà ṣì ń ṣẹ̀jẹ̀, nitori àwọn ìjà abẹ́nú tó ń bà á fínra.

Wọn ni laasigbo si n waye lorilẹede naa lai naani gbogbo ìwé àdéhùn àláfíà tí Ààrẹ Salva Kiir àti alátakò rẹ̀, Riek Machar tọwọ́ bọ̀.

Àjọ ìlà oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀, IGAD ní onírúurú ìpèníjà ni àdéhùn náà ń kojú, tó fi mọ́ ọ̀rọ̀ lórí kíkọ ìwé òfin tuntun fún orílẹ̀ èdè náà àti pípalẹ̀mọ́ fún ètò ìdìbò.

Aṣojú IGAD ní South Sudan, Ismail Wais ní IGAD kò le ní ìsinmi nígbà tí South Sudan ń gbóná janjan tó sì rọ àwọn àjọ àgbáyé láti ṣe àtìlẹyìn fún ètò àláfíà tó ń lọ lọ́wọ́ ní South Sudan.

Àkọlé fídíò, Omar Al-Bashir ti wọ́n gbajọba lọ́wọ́ ẹ ló di wàhálà

Ó ní ìrètí wà pé ìgbìmọ̀ tí yóò mú àyípadà bá ètò ìjọba tí ìjóba gbe kalẹ̀ lẹ́yìn ìwé àdéhùn náà yóò mú òpin bá ìjà tó ń wáyé tó sì ti ṣe ikú pa ọ̀pọ̀ ènìyàn, tí àwọn mìíràn sì di aláìnílí lórí mọ́.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ni Ààrẹ Salva Kiir ti kéde pé ètò ìdìbò yóò wáyé láì ṣe ètò ìkànìyàn ṣùgbọ́n tí Machar tako ìpinu yìí.

Machar ní ètò ìdìbò kò ní wáyé bí kò bá sí àjọ ọmọ ogun tó dúró ire, kí ìwé òfin mìíràn jẹ́ kíkọ, kì ètò ìkànìyàn wáyé àti ríri pé àwọn tó ń ṣe àtìpó ní orílẹ̀ èdè mìíràn padà sílé láti kópa níbi ètò ìdìbò.

Àkọlé fídíò, Bukola Odufuwa: Mo ń ta oúnjẹ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, gbálẹ̀, fọ aṣọ, pọnmi láì tọrọ agbe jẹun