Ukraine's Russia invasion: Ẹ̀rù ń ba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà tó wà ní Ukraine lórí ìkọlù Russia

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ àwọn akẹkọọ ọmọ Naijiria to n kẹkọọ lorilẹ ede Ukraine lo wa ninu ibẹru bojo bayii lẹyin ti Russia bẹrẹ si ni yin ado oloro si Ukraine.
Ni Ọjọbọ ni Aarẹ Vladimir Putin kọkọ yin ado oloro si ẹkun ila oorun Donbas.
Putin sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan pe k'awọn sọja ọmọ ilẹ Ukraine to n koju awọn ọm'ogun ọlọtẹ ti Russia n ṣatilẹyin fun jọwọ ara wọn, ki wọn sì pada sile jẹjẹ.
Aarẹ Putin ni oun ko gbero lati gba Ukraine, amọ ẹnikẹni to ba da si ọrọ naa, yoo da ara rẹ lẹbi.
- Ṣé lóòtọ́ ni Olubadan tuntun, Lekan Balogun buwọ́lu Tinubufun ipò arẹ lọdun 2023?
- Wo ọ̀pọ̀ àwòràn nípa ogun tó ń wáyé láàrin Russia àti Ukraine
- Kí ni Russia ń fẹ́ ní Ukraine?
- Èèyàn méje kú, ọ̀pọ̀ farapa bí Russia ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sí Ukraine
- UK fófin de bánkì márùn ún pẹ̀lu olówó Russia mẹ́ta torí làásìgbò Ukraine
Wo die ninu awọn akẹkọọ ọmọ Naijiria to wa ni Ukraine ti won wa ninu ibẹru
George Samuel Woedey to jẹ ọkan lára àwon akẹkọọ ọmọ Naijiria ni Ukraine sọ pe "ẹru n ba wa, a ko si mọ ohun to le ṣẹlẹ si wa tori nkan o fara rọ ni Ukraine lọwọ yii.
Ni bayii, emi at'awọn akẹgbẹ mi n gbero lati gba ibode oriilẹ kuro ni Ukraine nitori baalu ko le fo bayii.
Woedey to n gbe ni olu ilu Ukraine ni Kyiv sọ pe orile-ede Poland ni awọn fẹ morile.
Lati Poland ni awọn yoo ti wọ baalu lọ si Dubai.
- Ìyá Sunday Igboho wà lórí àìsàn torí kò rí ọmọ rẹ̀ - Agbekoya
- "A ti ṣetán láti gbógun ti ikú àìtọ́jọ́ tó ń pa àwa akẹ́kọ̀ọ́ fásitì OAU"
- Ọ̀pọ̀ àgbà òṣèré tíátà péjú sí Ede láti sin Tafa Oloyede déle ìkẹyìn
- Obìnrin tó bá purọ́ gbowó torí àyájọ́ olólùfẹ́, le fi ẹ̀wọn ogún ọdún jura - Amòfin
- Iṣẹ́ So-bàtà ní bàbá mi fẹ́ kí ń kọ́ ní Agbeni, kí ń to gba oko eré tíátà lọ - Iya Ibadan Sneh
- Davido, bá mi kọ ẹsẹ orin kan nínú àwo orin mi, jẹ́ ká da ayé láàmú - Portable Zazzu
- Mo fẹ́ ṣe ìyàwó pẹ̀lú ọmọọbabìnrin Ado Bayero ní Kano àmọ́ ń kò tíì mú ọjọ́ - Oluwo
Ninu ibẹru bojo ni gbogbo eeyan wa nibi lati igba ti wahala Russia ati Ukraine ti bẹrẹ.
Onikaluku lo n sa kijo kijo lati wa ọna kuro ni Ukraine ni kiakia."
Emmanuel Ibrahim to n kẹkọọ ni fasiti ti wọn ti n kẹkọọ nipa baalu wiwa ni ọkan oun ko balẹ mọ lati igba ti Russia bẹrẹ ikọlu si Ukraine.
O ni ẹru n ba gbogbo eeyan, koda, gbogbo ile ifowopamọ ni wọn ti kogba sile.
O ni Russia tun ti bẹrẹ si ni kọlu ilu kan to sun mọ orilẹ ede Poland ti awọn eeyan n gba kuro ni Ukraine lẹyin ti baalu ko le fo mọ.
Ibrahim ni ibi ti oun le sa si wa nile ẹkọ oun, amọ oun ko lanfaani lati de ile ẹkọ naa mọ tori Russia ti n ṣe ikọlu si ayika ile ẹkọ oun.
-Ijọba Naijiria sọrọ lori ikọlu Russia si Ukraine.
Kini ijoba Naijiria n sọ lori iṣẹlẹ naa?
Ijọba orilẹede Naijiria ti fi dáwọn ọmọ ilẹ naa to wa Ukraine loju pe oun ṣetan lati ko wọn kuro kete ti awọn papakọ ofurufu ba ti di ṣiṣi pada.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ilẹ okeere, Francisca Mayuli to fọrọ yii lede sọ pe olu ileeṣẹ ijọba Naijiria ni Ukraine sọ pe ko s'ewu fawọn ọmọ Naijiria to wa ni Ukraine.
O ni olu ileeṣẹ ijọba Naijiria to wa ni Ukraine tun sọ pe awọn ileeṣẹ ologun Ukraine ni Russia n ṣe ikọlu si.
Ẹwẹ, ṣaaju ni olu ileeṣẹ ijọba Naijiria ni Ukraine ti fi awọn nọmba ipe pajawiri tawọn ọmọ Naijiria le pe sita ti wọn ba ni idojukọ kan tabi omiran.















