Valentine: Amòfin kan ti ṣàlàyé ìjìyà tó wà fún ìwà ìtànjẹ àti àìmú ìlérí ṣẹ lábẹ́ òfin lásìkò àyájọ́ olólùfẹ́

Oríṣun àwòrán, Chesnot/Getty Images
Gbogbo ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù keji ọdọọ́dún jẹ́ ọjọ́ àyájọ́ olólùfẹ́ káàkiri àgbáyé èyí tí a mọ̀ sí valentine.
Ní àyájọ́ ọjọ́ yìí, àwọn olólùfẹ́ máa ń gbé ara wọn jáde, ra ẹ̀bùn fún ara wọn, tí wọn sì máa ń ṣe onírúurú nǹkan pẹ̀lú ara wọn.
Yàtọ̀ sí àwọn olólùfẹ́, àwọn òbí sọ́mọ, ọ̀rẹ́sọ́rẹ̀ẹ́, ẹ̀gbọ́n sí àbúrò náà máa ń ṣàmì ayẹyẹ ọjọ́ yìí nípa fífún ara wọn lẹ́bùn.
- Ṣé ìyàwó ilé tàbí àlè níta ló yé kí ọkùnrin lo 'Valentine' rẹ̀ pẹ̀lú?- Mercy Aigbe
- Wo ǹkan márùn ún tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò fẹ́ ní 'Valentine' 2021
- Ìdí tí mo fi ní ọ́jọ́ ikú ni ọ̀la ọjọ́ Valentine fún àwọn kan - Mike Bamiloye
- Ṣé lóòtọ́ ni omidan yìí ya wèrè ní kété tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ní òun fẹ́ fi ṣaya?
- Aṣọ ń pe aṣọ ráńṣẹ́ láàrin àwọn òṣèré tíátà ní àyájọ́ olúlùfẹ́
- Ọ̀nà ọ̀tọ̀ ni àjọ EFCC àti NYSC gbé àyájọ́ olólùfẹ́ ọdún 2020 gba
- "Ẹ̀yin obìnrin, ẹ fi òdòdó ṣe ẹ̀bùn ọjọ́ olólùfẹ́ fún ọkùnrin dípò kẹ gbà kó já òdòdó ara yín"
Bí ọjọ́ yìí ṣe máa ń jẹ́ ọjọ́ ìdùnnú fún àwọn olólùfẹ́ mìíràn, náà ni ó máa ń jẹ́ ọjọ́ ìbànújẹ́ fún ẹlòmíràn nítorí ọ̀pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin ni wọ́n máa ń purọ́ gba owó lọ́wọ́ ara wọn lásìkò yìí.
Ẹ̀wẹ̀, bí ó ṣe kù ṣáátà kí ọjọ́ yìí pé, ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ àwọn agbẹjọ́rò (NBA) tẹ́lẹ̀ rí, Douglas Ogbankwa tí ṣèkìlọ̀ fún àwọn obìnrin pé ẹnikẹ́ni tó bá pa irọ́ gbowó lọ́wọ́ ọkùnrin ló ṣeéṣe láti fi ẹ̀wọ̀n ogún ọdún gbára.
Obìnrin tó bá purọ́ gbowó torí àyájọ́ olólùfẹ́, le fi ẹ̀wọnogún ọdún jura:
Ogbankwa nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan ní, ọ̀pọ̀ obìnrin ló máa ń gbìyànjú láti purọ́ gbowó lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin lásìkò ayẹyẹ yìí tí wọn yóò máa fi ìfẹ́ irọ́ bojú.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tó ń ṣe èyí kò mọ̀ pé ìjìyà wà fún ìtannijẹ ati àìmú ìlérí ṣẹ lábẹ́ òfin tó de èrú ṣíṣe (419).
Ogbankwa tẹmpẹlẹ mọ pé obìnrin tó bá gba owó ọkọ̀ lọ́wọ́ ọkùnrin, tó sì mọ̀-ọ́n-mọ̀ kọ̀ láti lọ síbi tó gba owó rẹ̀, ni wọ́n le wọ́ lọ sí ilé ẹjọ́ lábẹ́ òfin yìí.
Bákan náà ló fi kun pé, ẹni tí ó bá gba irú owó bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú èròńgbà láti gba àlékún lọ́wọ́ ẹni bẹ́ẹ̀ tó bá dé ibẹ̀, náà ní ìjìyà lábẹ́ òfin.
Ó tẹ̀síwájú pé àjọ EFCC tàbí ICPC ló le gbé irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ sí ilé ẹjọ́.
Ó ní àyájọ́ Olólùfẹ́ jẹ́ àṣà àti ìṣe àwọn ìran kan, kò yẹ kí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí ta àbùkù rẹ̀ àti pé òfin kò fàyè gba mi ò mọ̀.

Oríṣun àwòrán, Thinkstock
Kí ni Valentine?
Àyájọ́ Olólùfẹ́ tí wọ́n ń pè Valentine's Day tàbí Saint Valentine Day lédè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n máa ń ṣayẹyẹ ní gbogbo ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù keji ọdọọ́dún.
Ayẹyẹ yìí wáyé láti bu ọlá fún àwọn ọmọlẹ́yìn Kírísítì kan tí wọ́n ṣekúpa nítorí ìgbàgbọ́ wọn láyé àtijọ́.
Onírúurú ìtàn ló rọ̀ mọ́ ìtàn Valentine ṣùgbọ́n lára èyí tó gbajúmọ̀ ni ti ìtàn Saint Valentine ilẹ̀ Róòmù tí wọ́n sọ sẹ́wọ̀n ní sẹ́ńtúrì kẹta fún ẹ̀sùn pé ó ń polongo ẹ̀sìn Kírísítẹ̀nì.
Ọdún 496 AD ní Pope Gelasius dá ayẹyẹ náà sílẹ̀ láti bu ọlá fún Saint Valentine ilẹ̀ Róòmù tó kú ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù keji, ọdún 269.
Láti ìgbà náà ni ayẹyẹ yìí ti ń gbèrú sí i di ohun tí àwọn ènìyàn ti ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn pàápàá láàárín àwọn olólùfẹ́.


















