Day before Valentine: Àyànmọ́ ẹlòmíì yóò bàjẹ́ lóríi bẹ́ẹ̀dì ní ọ̀la- Mike Bamiloye

Mike Bamiloye

Oríṣun àwòrán, Getty Images, Mike Bamiloye

Ilumọọka ajihinrere to tun jẹ oṣere fiimu Kristni, Mike Bamiloye ti sọ oko ọrọ sita lori ọrọ ayajọ ololufẹ ti ọpọ mọ si Valentine.

O sọrọ naa ni ayajọ ololufẹ ku ọla lọdun to lọ ni bi awọn mii ṣe n gbaradi fun ayajọ ọjọ ololufe ti o maa n waye ni ọjọ kẹrinla, oṣu keji ọdun.

Oṣere naa kọ imọran ati akiyesi rẹ bi ẹni n kọ itan ere ori itage ni pe:

"Irọle ọla jẹ ọjọ faaji, nigba ti awọn ọkunrin ati awọn ọdọbinrin yoo ba ayanmọ ọpọlọpọ jẹ lori ibusun ifẹkufẹ ara".

Bamiloye ni nigba ti ilẹ ọjọ keji yoo fi mọ, nkan ti dahun. "Ayanmọ yoo di tita fun ọdọkunrin tabi ọdọbinrin to ti ta ọjọ iwaju rẹ fun eṣu".

Bawo ni ọrọ ayajọ ololufẹ ṣe kan Josẹfu?

Mike Bamiloye, Gbajugbaja oṣere yii fi apẹrẹ ọrọ naa we Josẹfu ninu Bibeli to ni ayanmọ rẹ ko ba ti di gige kuru to ba jẹ pe o ba iyawo Potiphar to jẹ ọga rẹ lajọṣepọ.

O fi sita lori ayelujara pé "ẹ ku ayajọ ọjọ ololufẹ...!

Bi o ba ṣe pe Josẹfu ba iyawo Portiphar ni ajọṣepọ,

ko ba ma de aafin to ti di ọba to si ri iru opgo to ri".

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

Bamiloye ni Josẹfu moribọ lọwọ panpe ti ko ba mu u da ayanmọ rẹ legbodo eyi ti aye ọpọlọpọ eeyan ni ilu naa ati iran rẹ dara le lori".

Ọgbẹni Mike Bamiloye ni itan ọmọkunrin kan ni Bibeli toun naa ṣe "Valentine" ninu iwe Oniwaasu ori ikeje, ẹsẹ ikẹfa si ikẹtadinlọgbọn jẹ itan ibanujẹ.

Àkọlé fídíò, Kiki Osinbajo: T;o bá yá owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, máa gbìyànjú láti da padà

Bamiloye ni: "O ti ro pe oun fẹ gbadun alẹ ọjọ naa, o ti ro pe oun yoo jaye ori ara oun amọ o doju ọjọ iwaju ara rẹ bolẹ po lalẹ ọjọ igbadun kanṣoṣo.

"Oniwaasu 7:21-23

21 Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà;

ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.

Àkọlé fídíò, Damilọla pàdánù ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ nítorí ilà kíkọ

22 Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà,

bí i màlúù tí ń lọ sí ibùpa,

tàbí bí (aṣiwèrè) àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi ọgbọ́n ìfabà kọ́.

Àkọlé fídíò, Yinka Ayefele: Ìrọ́ ni pé ń kò le ṣe bíi ọkùnrin, mò ń ta pútú dàadáa

23 Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀,

bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn,

láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.