50 Year old Ajayi Folashade: Ilorin Grammar School gba ìyá àgbà yìí wọlé sí Jss 2

Àkọlé fídíò, 50 Year old Ajayi Folashade: Mo ti kọ́kọ́ dán an wò ní 80s àmọ́, ó kàn ṣáà ń wù mi náà ni

Ajayi Folasade lorukọ iya to jẹ ẹni aadọta ọdun to n kawe lọwọ ni ileewe girama Ilorin Grammar School, IGS.

Nigba ti BBC Yoruba gbọ nipa iya yii, lara ohun taa gbọ to wu wa lori lati wa arabinrin Folashade kan ni pe o pinu lati maa ba awọn ẹgbẹ ọmọ-ọmọ rẹ jokoo pọ ni kilaasi tori imọ to fẹ ni.

"Igba ti gbogbo igbiyanju mi lati kawe n bọ si pabo, mo lọ si ileewe ti ijọ kan to wa lẹgbẹ ile wa ni 2012 ti mo si maa n jokoo pẹlu awọn ọmọde to wa nibẹ".

Ajayi Folasade

Folashade ni nigba ti oun tun gbọ ti awọn ajọ kan loun tun lọ darapọ mọ wọn ti oun si gba iwe ẹri kika ileewe alakọbẹrẹ ja.

Iroyin sọ pe o lọ forukọ silẹ lati darapọ mọ kilaasi onipele ikeji, Jss 2 tori o wu u lati kawe ki oun naa si di olukọni lọjọ kan.

O wu u lati jẹ moriya fun awọn agbalagba to jẹ ẹgbẹ tirẹ naa lati ma jẹ ki ala wọn wọmi lai fi ti ọjọ ori wọn ṣe.

Ajayi Folasade

"2017 ni mo bẹrẹ 'Secondary'".

Adari ileewe IGS, Alhaji Abdulrahman Akeyede sọ fun BBC Yoruba pe oun ka gbogbo ofin ati alakalẹ ti mama agba yii yoo tẹle fun un nigba to wa fun ibeere.

"A ran 'uniform' fun iya, iya si bẹrẹ kika iwe rẹ pẹlu wa".

Ajayi Folasade

Nibayii, ileeṣẹ eto ẹkọ ni ipinlẹ Kwarra gan ti ni iwuri ni igbesẹ arabinrin naa jẹ ni ọjọ ori rẹ.

Olukọ kilaasi "Anti Ṣade" gẹgẹ bi wọn ṣe maa n pe e sọ pe o ya awọn lẹnu pe o n ṣe deedee ni kilaasi.

Ọmọdekunrin to tun jẹ Balogun kilaasi anti Ṣade sọ pe iru wọn lawọn n fẹ ni ileewe tori awọn fẹran wọn bi wọn ṣe n jafafa ninu kilaasi.