Iya Ibadan Sneh: Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, 'Iya Ibadan Sneh' ní iṣẹ́ bàtà ṣíṣe lòun kò bá ṣe gẹ́gẹ́bí bàbà òun ṣe fẹ́

Oríṣun àwòrán, Iyaibadansneh
Ọpọlọpọ awọn ololufẹ gbajumọ oṣere tiata apanilẹrin Rukayat Sọliu Lawal ti ọpọ mọ si 'Iya Ibadan Sneh', ni ko mọ pe diẹ lo ku ki wọn padanu ohun gbogbo ti wọn n ri dunu ninu awọn ere sinima to ti n kopa.
Gbajumọ oṣere tiata naa ṣalaye pe lati kekere ni oun ti ṣakiyesi ẹbun oun ṣugbọn awọn ẹbi oun ko figba kankan fọwọ sii ki oun di oṣere tiata rara.
- Ìyá Sunday Igboho wà lórí àsàn torí kò rí ọmọ rẹ̀ - Agbekoya
- Afurasí ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn yìnbọn pa akẹ́kọ̀ọ́ tó ń múra NYSC àti ọlọ́kadà l'Ẹdẹ
- Àwọn tó ní mi ò lè bímọ lárùn ọpọlọ, ó nídìí tí mo fi ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ - Yomi Fabiyi
- Mo fẹ́ ṣe ìyàwó pẹ̀lú ọmọọbabìnrin Ado Bayero ní Kano àmọ́ ń kò tíì mú ọjọ́ - Oluwo
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu iwe iroyin Nigeria Tribune, Iya Ibadan Sneh ni, baba oun ni paapaa julọ, ko fọwọ sii rara nitori iṣẹ tiata ko tii gbowolori bi ti isinyi.
O ni iṣẹ so-bata-so-bata ni baba oun n fẹ ki oun lọ kọ lagbegbe Agbeni nilu Ibadan nigba naa, ṣugbọn ti oun faake kọri pe, bi baba oun ko ba ti le tọ oun lọ sile ẹkọ, a jẹ pe ọna oko ere tiata ni oun yoo kuku morile nigba naa.

Oríṣun àwòrán, Iyaiobadansneh
Bakan naa lo fi kun un pe, ọkan lara awọn ọmọ iya oun kan naa die tako o gidigidi ni.
Amọṣa, nnkan ti yi pada bayii gẹgẹ bi iya Ibadan ṣe sọ.
'Bayii, oun gan ni n pe mi lati beere igba ti sinima mi miran yoo tun jade.
Koda, kii pa eyikeyi sinima mi jẹ rara. A tilẹ tun maa fi mi yangan ni ilẹ Gẹẹsi to wa bayii pe, oun ni ọmọ iya kan to n ṣe sinima ni Naijiria."

















