Adunni Ade: Lóòtọ́ọ́ ní àwọn adarí eré máa ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré-bìnrin àmọ́ kò ṣẹlẹ̀ sí mi

Àkọlé fídíò, Adunni Ade: Lóòtọ́ọ́ ní àwọn adarí eré máa ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré-bìnrin

Ilumọọka osere tiata ni ede Yoruba ati Gẹẹsi, Adunni Adewale, ti ọpọ eeyan mọ si Adunni Ade ti salaye lẹkunrẹrẹ nipa igbe aye rẹ.

Adunni lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, sọ diẹ nipa awọn ohun to ti la kọja ninu ẹbi ati lẹnu isẹ tiata pẹlu isesi awọn akẹẹgbẹ rẹ.

Bakan naa lo sisọ loju rẹ pe lati kekere ni oun ti pinnu lati sisẹ ẹni ti yoo maa da awọn eeyan lara ya, ti ko si wu oun ri lati sisẹ dokita tabi agbẹjọro.

Ile iwe ni mo wa ti mo fi gba oyun:

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, Adunni Ade, tii se akọbi fawọn obi rẹ salaye pe ile ẹkọ ni oun wa, ti oun fi gba oyun eyi to bi awọn obi oun ninu gidigidi.

“Nnkan ti wọn ran mi lọ se kọ niyẹn, gẹgẹ bẹ se mọ pe awọn obi nilẹ Afirika maa n fẹ ki ọmọ ka iwe, ko gba oye imọ ijinlẹ amọ ti temi ko ri bẹẹ.

Se ni mo fo gbogbo eleyi, boya bi Ọlọrun se kọ irin ajo temi niyẹn.”

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lootọ ni awọn adari ere tiata maa n ni ajọsepọ pẹlu awọn osere tiata:

Adunni Ade tun fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ọrọ to n gbalẹ kan pe awọn Adari ere tiata maa n bawọn osere-binrin lo ifẹ ikọkọ, ki wọn to fun wọn ni ipo ninu ere.

“Lootọ lo maa n sẹlẹ bẹẹ, a ti maa n gbọ, mo tiẹ mọ awọn eeyan ti iru eyi sẹlẹ si.

Ko sẹlẹ si emi ri amọ a mọ awọn eeyan to n se daadaa, tori rẹ ni mo se maa n gba awọn obinrin to ba fẹ inu isẹ wa nimọran pe ki wọn ohun ti wọn n se.

ẹ ma titori pe ẹ fẹ jẹ ki awọn eeyan tete mọ yin, kẹ ti maa sare bọ asọ, pe ẹ fẹ ba awọn eeyan kan ni ajọsepọ tori kẹ le tete wọ inu sinima.

Ẹ di Ọlọrun yin mu, kẹ si di isẹ yin mu, kẹ si gbaju mọ ibi tẹ fẹ de ati ibi tẹ n lọ, kii se pe kẹ maa gbe ara yin silẹ fun kunrin.”

Awọn ipenija wo ni Adunni ti koju ninu isẹ sinima?

Adunni salaye pe oun kii sere nibi ti oun ti n jẹun, oun ko si ri aaye lati maa sọ ọrọ idọti kaakiri.

O ni bi ile aye toun se maa dara ni oun kọju mọ.

“Mo maa n fẹ koju awọn ere ti yoo fun mi ni ipenija, ti awọn oludari ere miran si maa n fẹ ki n pa owe.

Ko si si ojuse to le ti wọn fun mi ninu ere, ti n ko kii tiraka lati se daadaa.

Awọn kuku n wo sinima ta n se, ti wọn si ni mo n gbiyanju, iyẹn gangan ni koko.

Mo si ti gba oniruru ami ẹyẹ lorisirisi fawọn isẹ ti mo se.”

Ta ni Adunni Ade?

Adunni Adewale, ti ọpọ eeyan mọ si Aduuni Ade ni wọn bi silu New York lorilẹede Amẹrika.

Ọmọbibi Ireland ni iya rẹ nigba ti baba rẹ jẹ alawọ dudu lati ilẹ Yoruba.

Ọmọ ọdun meji lo ti pada wa si Naijiria pẹlu awọn obi rẹ lati wa se ayẹy oku baba baba rẹ, ilu Eko si lo gbe dagba to fi di ọmọge.

Amọ o tun pada sorilẹede Amẹrika lati lọ sile ẹkọ fasiti nibẹ.

Gbajumọ osere tiata ni ni ede oyinbo ati Yoruba ni orilẹede Naijiria, to si tun maa n sisẹ asaraloge.