Yinka Ayefele: Ìrọ́ ni pé ń kò le ṣe bíi ọkùnrin, mò ń ta pútú dàadáa
Awọn agba ni ẹni ti yoo ga, ẹsẹ rẹ yoo tiirin, bẹẹ si ni bi ẹni ti yoo ba ni ogo, yoo ri ohun sọ nitori inu ẹgbin ni ọla n gbe.
Idi ree ti ilumọọka akọrin ẹmi Tungba nni, Ọmọwe Olayinka Joel Ayefele (MON) fi n se alaye ọpọ ohun ti oju rẹ ri, ko to di eeyan lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ.
Ayefele, ninu ifọrọwerọ naa, tun salaye bo se bẹrẹ igbesi aye rẹ, awọn isẹ to ti se, ko to ja oju ọna pẹlu bo se ni ijamba ọkọ to da joko sori kẹkẹ lai le rin.
- Yinka Ayefele di bàbá ìbẹta
- Yinka Ayefele di asojú Àjọ INEC
- Háà, nǹkan ṣe mí! Ikú pa ọ̀kan lára àwọn aláànú mi - Yinka Ayefele
- Ìrọ̀rùn dé! Yinka Ayefele le è dúró kọrin pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ tuntun
- Yinka Ayefele ṣe ìkọ́mọ ìbẹta rẹ̀, ọ̀nà ò gbẹsẹ̀
- Nàìjíríà ni ìkómọ àwọn ìbẹ́ta mi yóò ti wáyé lẹ́yìn tí mo bá gba páálí wọn l'Ámẹ́ríkà
- Ayefẹlẹ bá BBC sọ̀rọ̀ lórí ilé orin rẹ̀ tí Ajimọbí ń tún kọ́
- Owó tí Dino nà kò tilẹ̀ tó ra epo sí gẹnẹrétọ̀ tí a fi kọrin - Ayefele
- Davido, Pasuma àti Yinka Ayefele dábírà lópin ọ̀sẹ̀, aráyé múgbe bọnu
- Ayefele fi orin ẹ ṣeun sẹ́nu kí Ajimobi
- Davido yàtọ̀ s'àwọn ọ̀dọ́ olórin kan tó lè yẹ̀yẹ́ àgbà olórin, òun ló kọ́kọ́ ná mi ní béèlì N1M lágbo - Yinka Ayefele
Bakan naa ni gbajumọ akọrin ẹmi ati agbohunsafẹfẹ naa tun sọrọ lori oniruuru ahesọ ọrọ tawọn eeyan n gbe kiri nipa oun lati igba ti ijamba ọkọ naa ti waye.
Nibo ni Ayefele ti bẹrẹ isẹ oojọ ni aarọ ọjọ?
Ayefele salaye fun BBC pe ileesẹ redio ijọba apapọ, ta mọ si Radio Nigeria ni oun ti bẹrẹ isẹ ni ibẹrẹ aye oun.
O ni isẹ ki oun maa ba wọn gbe baba Keresi lopin ọdun ni oun kọkọ fi bẹrẹ lọdun 1997, ti wọn si n fun oun ni aadọta naira ni ojumọ.
O salaye pe asiko yii ni wọn ri ẹbun ohun agbohunsafẹfẹ lara oun, ti wọn si gba ki oun maa se eto lori redio wọn.
O ni awọn ẹbun orin ti ohun tun ni tẹlẹ tun ni oun n lo lati maa mu owo wọle nibẹ nipasẹ ipolowo ọja ati ikede, ti oun si pade oloogbe Kola Olawuyi nibẹ.
Mo ti ta Gita pẹlu awọn agba akọrin Juju ri:
Ayefele tẹsiwaju pe oun ti sisẹ atagija lẹyin awọn agba osere olorin ri, lara wọn ni Baba Toye Ajagun, Wale Thompson, Micho Ade ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O ni oun tun maa n ba awọn ile ijọsin ta gita kaakiri lasiko isin pẹlu, ki oun to wa yan isẹ agbohunsafẹfẹ ni aayo.
Bawo ni irinajo orin kikọ se bẹrẹ fun Yinka Ayefele?
Olayinka Ayefele ni ọjọ Kejila osu Kejila ọdun 1997 ni ijamba se elesu lẹyin ọkọ fun oun, ti oun si bẹrẹ irin ajo orin kikọ.
“Osu mọkanla ni mo lo nile iwosan UCH nilu Ibadan fun itọja ara lasiko ti mo ni ijamba ọkọ naa, ti mo si maa n da gbọ awọn orin kekeke ti mo ti kọ tẹlẹ́.
Awọn kekeke yii ni mo n gbọ lasiko ti awọn ọrẹ mi wa ki mi, ti wọn si gbe imọran kalẹ pe ka se akojọpọ awọn orin naa, ka si se ifilọlẹ rẹ lati ri owo.
Owo yii ni wọn ni maa lo lati lọ fi se itọju ara mi ni oke okun, ti mo si gbe awo orin Bitter Experience jade.
Amọ awọn eeyan tẹwọgba orin naa, ti mo si ri pe ọbẹ wa nibẹ, bi mo se bẹrẹ niyẹn.
Kii se oogun okiki ni mo se, ti mo fi di ẹni ori kẹkẹ, ẹhun ọrọ lasan ni:
Nigba to n sọ nipa ọpọ ahesọ ọrọ ti awọn eeyan n sọ nipa bo se di olokiki lẹyin to ni ijamba ọkọ tan, Ayefele ni ahesọ ọrọ lasan ni awọn ọrọ naa.
“Se o rọrun ki eeyan fi igbesi aye rẹ se oogun okiki tori ko le lowo, ko joko sori kẹkẹ, rara, ko ri bẹẹ.
Wọn tun ni mo fi eegun ẹyin mi se oogun okiki ni, ki n wa ni ori kẹkẹ lo wu mi ki n joko si, ẹhun ọrọ lasan ni
Koda, wọn tun sọ pe o seese ki n ma le se bii ọkunrin amọ ko ri bẹẹ, mo le se daadaa.”
Ta ni Yinka Ayefele?
Olayinka Joel Ayefele jẹ akọrin, agbohunsafẹfẹ ati oludasilẹ ileesẹ Redio kaakiri ilẹ Yoruba.
Ọmọ bibi ilu Ipoti Ekiti nipinlẹ Ekiti ni, to si dele aye ni ọdun ọjọ kinni osu Keji ọdun 1968, eyiun ọdun mẹrinlelaadọta sẹyin.
Ọdun 1997 lo ni ijamba ọkọ to kan eegun ẹyin rẹ, ti ko si le fi ẹsẹ mejeeji rin mọ, eyi to mu ko maa lo kẹkẹ.
Yinka Ayefele, ẹni ti ijba apapọ fi ami ẹyẹ MON da lọla lo ti gbe ọpọ awo orin jade, o ni iyawo, to si bi ibẹta.


