'Tayọ̀tayọ̀ ni mó fẹ́ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú INEC ki ìdìbò 2019 lé dára'
Yinka Ayefẹlẹ ba BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí ipò rẹ̀ tuntun gẹ́gẹ́ bii aṣoju INEC.
O mẹnuba iṣẹ to wa niwaju oun lati ṣe ki o le tubọ jẹ awokọṣe rere fawọn ọdọ.
Bakan naa ni ogbontarigi olorin naa fi imoore ati ayọ rẹ hàn fún amuyẹ pé oun lo tọ si lati ṣoju ajọ eleto idibo INEC.
Ayefẹlẹ ṣetan láti jẹ ki àwọn ọdọ mọ ojuṣe wọn lasiko idibo to m bọ.
Ni afikun, o kilọ fawọn ọdọ ki wọn ma jẹ ki ẹnikẹni lo wọn siwa jagidijagan lasiko idibo.
O ni ki wọn ranti pe, ọmọọlọmọ la n ran niṣẹ de toru toru, to ba di tọmọ ẹni wọn a ni tilẹ ba ṣu ọ koo sun si ọhun ni.
Eyi tumọ si pe ki wọn ma jẹ ki oloṣelu kankan lo awọn nilo ọmọ buruku nigba ti wọn n fi awọn ọmọ ti wọn pa mọ.
Ni ipari, Ayefẹlẹ ke si gbogbo awọn oṣere ati onkọrin pe ki won jẹ ki awọn jọ fọwọsowọpọ lori ohun to yẹ ni ṣiṣe lori idanilẹkọ ati ilanilọyẹ lori agbara oludibo ninu idibo 2019 to m bọ lọna ni Naijiria.