Ilé orin wa tí Ajimobi tun kọ́ dára púpọ̀, ṣùgbọ́n a kò ní dẹ́kun òtítọ́
Lẹyin oṣu mẹta ti Ijọba Ipinlẹ Oyo wo ileeṣẹ orin Yinka Ayefele to wa ni Challenge, Ibadan, o ti dupẹ lọ́wọ́ Gomina Ipinlẹ naa, Abiola Ajimọbi, bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko ni dẹkun lati maa sọ ootọ ọrọ to maa ṣe ara ilu lanfani.
O sọ fun BBC Yoruba pe eyi ti ijọba kọ wayi tile dara ju ti eyi ti wọn wo lọ.
Ẹ o ranti wipe oṣu kẹjọ ni Ipinlẹ Oyo wo ileeṣẹ orin naa latari pe ko gba iwe to tọ. Igbesẹ naa bi awọn ara ilu ninu gidi.
Ṣugbọn Ayefele ni oun ko ba ijọba ja, bẹẹ ni oun ki i ṣe ọta Ajimọboi.