Yinka Ayefele kò leè fi ìdúnú rẹ̀ pamọ́ lọ́jọ́ ìkómọ ìbẹta rẹ̀

Awọn ọba, oloṣelu, àwọn ọ̀tọ̀kúlú ìlú yẹ́ àwọn ìbẹta t'Ọ́lọ́run fi ta gbájúgbajà olórin Yinka Ayefele lọ̀rẹ níbi ìkómọ wọn.
Ninu oṣu keje ọdun 2019 ni Yinka Ayefele ko le pa ore naa mọra to si tu iroyin ayọ naa sita pe Ọlọrun ṣe idile ohun loore nla.
Nibi ikomọ awọn ibẹta yii, kii ṣe ọrọ ero pẹpẹpẹ tabi wẹ́wẹ́, ẹsẹ̀ ko gbero sibẹ awọn molumọọka lawujọ gan wa dara pọ mọ ayẹyẹ naa.

Ṣaaju eyi ni awọn eeyan ti n gbọ finifini bii pe iroyin ẹlẹjẹ ni to sọ pe iyawo onkọrin yii bimọ ṣugbọn ti oun pẹlu tete bọ si igboro lati salaye pe iyawo oun ko tii bimọẸ dákẹ́ àhesọ ọ̀rọ̀, n kò bí ìbẹta - Yinka Ayefẹlẹ.
Ẹwẹ, nigba ti ọrọ naa di ohun, olorin yii ko bo ore Ọlọrun mọra lati igba to ti kọkọ fi oju awọn ọmọ mẹta naa hande. Lara ọna idupẹ rẹ ni isin ikomọjade to waye lọjọ aiku ọjọ kẹta oṣu kẹrinla ọdun 2019.

Lọjọ ikomọ naa, awọn mọlumọọka eeyan peju sibẹ. Pẹlu ayọ ati idunu ni wọn fi n yẹ iya, baba ati awọn gaan naa si.
Yinka Ayefele fi ọpọ ore rẹ han si awọn to wa sibi ikomọ awọn ẹta tó wọle tọ idile rẹ wa.










