Yinka Ayefele fi orin ẹ ṣeun sẹ́nu lórí ilé orin tuntun rẹ̀

Oríṣun àwòrán, yinkaayefele
Gbajúgbajà olórin tó tún jẹ́ alága ilé iṣẹ́ rẹ́díò Fresh FM nílùú Ibadan, yinka Ayefẹlẹ gbóríyìn fún Gómìnà Abiọla Ajimọbi pé ó tún ilé orin rẹ̀ kọ̀.
Nínú ọ̀rọ̀ tí mọ̀lúmọ̀ọ́ká olórin náà fi síta lọ́jọ́ ajé ni Ayefẹlẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ gómìnà Ajimọbi fún ìgbésẹ̀ yìí.
Ọdún 2018 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe ilé náà èyí tí wọ́n ti párí báyìí gẹ́gẹ́ bí àwọn oníròyìn ṣe jábọ̀.
Ṣáájú ni ìjọba Abiọla Ajimọbi wó lára ilé náà lulẹ̀ látàrí pé wọ́n ni Yinka Ayefẹlẹ rú òfin ìpínlẹ̀ tó ní ṣe pẹ̀lú ìlànà ilé kíkọ.
Ẹ̀wẹ̀, ìgbésẹ̀ yìí ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye káàkiri yálà láti gbè lẹ́yin ohun tí gómìnà Ajimọbi ṣe tàbí ta kò ó.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post









