Minimum wage: Gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà ní Nàíjíríà ní ìwọ́de NLC yóò ti wáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria ti kede pe lọjọ Isẹgun ni iwọde apapọ awọn oṣiṣẹ yoo bẹrẹ jakejado orilẹede Naijiria.
Dipo iyanṣẹlodi, eyi ti ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria n fọkan si tẹlẹ, ẹgbẹ oṣiṣẹ ni iwọde nikan ni yoo waye bayii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Atẹjade kan ti akọwe agba fun ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC lorilẹede Naijiria fi sita ni ''lẹyin ipade ti agbarijọpọ ẹgbẹ oṣiṣẹ gbogbo lorilẹede fi sita ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kejila ọdun 2018, ni ipinnu lati gunle iwọde dipo iyanṣẹlodi ti waye."
" Lẹsẹkẹsẹ ni a ti fi ikede sita pe, ni ọjọ Iṣẹgun, tii ṣe ọjọ kẹjọ oṣu Kinni ọdun 2019, iwọde apapọ yoo waye lati fi ẹhonu han kaakiri gbogbo ipinlẹ lorilẹede Naijiria. Ṣugbọn eyi ko tumọ si iyanṣẹlodi."
Agbarijọpọ ẹgbẹ oṣiṣẹ labẹ, NLC, TUC ati ULC n fi ẹhonu han lori bi ijọba apapọ ṣe kuna lati fi aba ofin nipa sisan ẹkunwo oṣu tuntun ranṣẹ si ile aṣofin apapọ fun lati fọwọsi.









