OAU Student's Death: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣàlàyé pé Heritage tó já sí sókàweè bọ́ síta láti sá aṣọ ni

Oríṣun àwòrán, Heritage Ajibola
Awọn akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo ni wọn bẹnu atẹnu lu awon alakoso Ilegbe Bver hostel, lẹyin ti akẹkọbinrin kan, Ajibola Heritage jẹ pe Ọlọrun.
Heritage lo jẹ akẹkọọ ọlọdun keji ni ẹka imọ ẹkọ ede ati ise ilẹ adulawọ, (Linguistics and Africa studies) nile ẹkọ fasiti Obafemi Awolowo.
Amọ se lo sasede bọ sinu koto ti wọn gbẹ fun igbẹ lati maa rogun si ta mọ si Soakaway.
- Ìyá Sunday Igboho wà lórí àìsàn torí kò rí ọmọ rẹ̀ - Agbekoya
- Ọ̀pọ̀ àgbà òṣèré tíátà péjú sí Ede láti sin Tafa Oloyede déle ìkẹyìn
- Obìnrin tó bá purọ́ gbowó torí àyájọ́ olólùfẹ́, le fi ẹ̀wọn ogún ọdún jura - Amòfin
- Iṣẹ́ So-bàtà ní bàbá mi fẹ́ kí ń kọ́ ní Agbeni, kí ń to gba oko eré tíátà lọ - Iya Ibadan Sneh
- Davido, bá mi kọ ẹsẹ orin kan nínú àwo orin mi, jẹ́ ká da ayé láàmú - Portable Zazzu
- Mo fẹ́ ṣe ìyàwó pẹ̀lú ọmọọbabìnrin Ado Bayero ní Kano àmọ́ ń kò tíì mú ọjọ́ - Oluwo
A gbọ pe Heritage lo n gbinyanju lati sa asọ to fọ sita, lasiko ti isẹlẹ naa waye.
Nigba ti ikọ iroyin BBC Yoruba kan si ile ti isẹlẹ ti waye, a fidi rẹ mule pe wọn ko fi ideri de ikoto naa lati fi sẹmẹnti di pa.
Bi Sokawe naa se si silẹ lo mu ki akẹkọbinrin naa ja bọ sinu rẹ, to si lo to wakati kan ki wọn to ri yọ.
BBC Yoruba gbọ pe awọn osisẹ Panapana to de sibi isẹlẹ naa lo yọ akẹkọ naa sita amọ asọ ko ba Ọ́mọyẹ mọ.
Idi ni pe Heritage ti jẹ ipe Ọlọrun ki iranwọ lati yọ sita ninu koto to de.
Kii se iku Ọlọrun lo n pa meji lara awọn akẹkọọ wa to ku:
Nigba ti iko iroyin BBC Yoruba se abewo si ile ti isẹlẹ naa ti waye, a ba awon akeko to wa ni agbegbe naa sọrọ.
Alukoro fun ẹgbẹ awọn akẹkọọ, Student Union ni fasiti OAU, Ogunperi Taofeek sọ pe ohun to ba ni lọkanjẹ ni isẹlẹ naa.
Ogunperi ni ẹgbẹ awon akẹkọọ si ti dide lati ri pe awọn ja fun idajo ododo lori iku Akeko naa.
- "Ìná tó ń ṣe àkóso ojú pópó ló dá ọkọ̀ agbówórìn dúró, tí adigunjalè fi kọ lù ú"
- Ìjà abẹ́nú bẹ̀rẹ̀ lẹ́gbẹ́ NURTW l‘Eko, nǹkan kò fara rọ
- Ẹ wo bí ‘dókítà’ ṣe yọ àpò ẹyin ilé ọmọdébìnrin kan lásìkò iṣẹ́ abẹ́
- Afurasí ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn yìnbọn pa akẹ́kọ̀ọ́ tó ń múra NYSC àti ọlọ́kadà l'Ẹdẹ
- Àwọn tó ní mi ò lè bímọ lárùn ọpọlọ, ó nídìí tí mo fi ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ - Yomi Fabiyi
O sọ̀ siwaju pe "kii se pe iku Ọlọrun lo n pa awọn akẹkọ akẹẹgbẹ wa, asise awọn ato ni ilegbe Bver hostel lo fa idi ti Heritage ko se si pelu wa mọ.
A si ti bẹrẹ ija fun idajọ ododo tori owo ti awon Akeko san fun awon ayani nile gbe naa nitori owo nla ti o to lati fi tọju ayika wọ ni wọn gba.
O si ti yẹ ki wọn pese gbogbo ohun eelo to ba yẹ sibẹ, laisi ipalara fun ẹnikẹni, ki won to fisita fun akeko lati gbe."
A padanu Timothy Adegoke, a tun ti padanu Heritage, ki lo de gan?
Awọn asaaju akẹkọọ ni fasiti OAU naa wa n gbarata lori iku aitjọ to n mu awọn akẹẹgb wọn naa lọ.
" Awa akeko ti wa dide pe o to ge, isele yii lo jẹ ekeji ti a padanu lara wa, bayi naa ni a se padanu Timothy Adegoke, ko to dipe Ajibola Heritage naa jẹ ipe Ọlọrun.
Won si ni iku to pa ojugba ẹni, owe lo pa fun ni. Idi niyi ti a fi dide lati ri pe a dẹkun isẹlẹ naa tori ọjọ iwaju."
Ibanujẹ ni fun wa lati padanu akẹkọọ wa - OAU
Bakanaa ni Iko BBC News Yoruba se Abewo si alukoro fasiti naa, Ogbeni Abiodun Olarewaju, to si salaye bi isẹlẹ naa se waye ati iha ti Ile iwe fasiti kọ si .
"Ibanujẹ lo jẹ fun wa lati padanu ikan lara awon akeko wa.
Ile iwe gbinyanju lati ri pe isẹlẹ naa o waye sugbon ko bọ si.
Bi a se gbọ nipa isẹlẹ yii, ni a tete ransẹ pe awon panapana lati ba wa yọ ọmọbinrin naa sugbon gbogbo igbinyanju naa ja si pabo."
"Awon Ilegbe akẹkọọ to wa lagbegbe naa ni o jẹ aladani, ti kii se ti Ile iwe fasiti wa.
A ti ransẹ pe awon obi ọmọ naa, ti won si ti wa yọju."


Oríṣun àwòrán, Deronke Eunice Abebi/Facebook
Akẹ́kọ̀ọ́ fásítì OAU dèrò ọ̀run nígbà tó já sínú kòtò ilé ìgbẹ́ 'soakaway'
Akẹkọọ ile ẹkọ gíga fasiti OAU, Ile Ife kan, Ajibola Heritage Ayomikun ti dero ọrun lẹyin to ja sinu "soakaway" to wa lẹgbẹ ileegbe awọn akẹkọọ to n gbe.
Ayomikun n kẹkọọ nipa oriṣiiriṣii ede ilẹ Afirika ni fasiti naa ki o to ṣagbako iku ojiji.
Ọdun keji ni Ayomikun wa lẹnu ẹkọ rẹ ni fasiti OAU ni Ile Ife.
- Ìjọba Oyo àti iléeṣẹ́ amúnáwá wọ̀yá ìjà torí gbèsè tí wọn jẹ ara wọn
- Wo orílẹ̀èdè míì l‘Áfíríkà tí ìfipá gbàjọba tún ti ń rúgbó bọ̀
- "Ẹ̀rù kí Naijiria má ti bodè lo n ba Benin Republic, tó ṣe mú Sunday Igboho mọ́lẹ̀"
- Àìsàn wo ló ń ṣe Opeyemi Ayeola tó tún fi dèrò ilé ìwòsàn?
- Small Mummy, aláwàdà ọmọ ọdún mẹwàá gba ẹ̀bùn ọkọ̀ olówó iyebíye
- Lóòótọ́ ní àṣìṣe wáyé lórí ìṣẹlẹ ìfipábọ́mọdélòpọ̀ nígbà tí mo wà lórí àkóso - Pope Benedict XVI
- Onímọ̀ ẹ̀yà ara míì kéde okùnfa ikú míràn tó pa Sylvester Oromoni
Ọrọ ti ile ẹkọ gíga fasiti sọ lori iṣẹlẹ naa:
Agbẹnusọ ile ẹkọ gíga OAU, Abiodun Olarewaju, sọ ninu atẹjade to fi sita pe lootọọ ni akẹkọọ ọhún ja sinu "soakaway" ni BVER to jẹ ileegbe awọn akẹkọọ aladani.
Olarewaju to fi aidunnu ile ẹkọ naa han lori iṣẹlẹ ọhun sọ pe iṣẹlẹ naa ṣeni laanu.
Olarewaju ni "kete ti a gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni a ran àwọn oṣiṣẹ adoola ẹmi lọ si ibẹ.
Amọ, ọwọ ti bọ sori nigba ti wọn gbe Ayomikun de ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun OAU, ẹlemii ti gba a.
Awọn oṣiṣẹ panapana gbiyanju agbara wọn lati yọ akẹkọọ naa jade ninu koto to já sí.
Ṣugbọn o ti gbẹmi mi ki wọn to gbe de ile iwosan."

Oríṣun àwòrán, Deronke Eunice Abebi/Facebook
Ọga agba ile ẹkọ fasiti OAU kẹdun pẹlu obi Ayomikun:
Ọga agba ile ẹkọ gíga fasiti OAU, Ọjọgbọn Eyitope Ogunbodede ko ṣai kẹdun pẹlu awọn obi Ayomikun lori iku ọmọ wọn.
Bakan naa ni Ọjọgbọn Ogunbodede tun daro pẹlu awọn ọrẹ ati akẹgbẹ akẹkọọ to di oloogbe.
Ọjọgbọn Ogunbodede ni iṣẹlẹ buruku gbaa ni iku Ayomikun jẹ.
O ṣeleri lati ṣe iwadii lori ohun to ṣe okunfa iku Ayomikun ati pe gbogbo awọn ti aje ọrọ naa ba ṣi mọ lori ni yoo foju wina ofin.
Ogunbodede rọ awọn akẹkọọ lati ma fa wahala nitori ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.




















