Sex Abuse: Lóòótọ́ ní àṣìṣe wáyé nípa bá ṣè kojú ìṣẹlẹ ifipabọmọdé l'òpọ̀ - Póópù

Oríṣun àwòrán, Reuters
Olori ijọ Aguda tẹlẹ Pope Benedict XVI ti jẹri si pe awọn kuna nipa bi wọn se n koju iṣẹlẹ ifipabamọdelopọ nigba to wa ni ipo archbishop ilu Munich.
Ninu iwe kan ti o fi ṣọwọ si Vatican, Poopu tẹlẹ yii tọrọ aforijin fun asiṣe to waye nigba naa, ṣugbọn ko gba pe oun ṣe aida.
Iwadii kan to jade ni Germany lo fẹsun kan pe, ijọ Aguda ko gbe igbesẹ to tọ ati to yẹ lori ẹsun ifipabamọdelopọ.
Nigba naa lọhun, Joseph Ratzinger lorukọ Poopu, to si jẹ arcbishop ilu Munich laarin ọdun 1977 si ọdun 1982.
Iwadii ile iṣẹ amofin ilẹ Germany yii sọ pe, niṣe ni iwa ifipabọmọdelopọ ṣi n waye labẹ akoso rẹ ati pe awọn wolii ti wọn fẹsun yi kan ṣi n ṣiṣẹ ni ile ijọsin.
Ninu esi rẹ akọkọ lori ẹsun wọnyi, Poopu tẹlẹ yii, to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelaadọrun sọ pe 'Wọn gbe ojuṣe nla fun mi nigba ti mo wa nile ijọsin Aguda.
O jẹ ibanujẹ fun mi bi mo ba ranti awọn aburu ati aṣiṣe to waye nigba ti mo wa lori akoso ''
O ṣe apejuwe iwa ti wọn hu si awọn ti wọn fipabalopọ yii gẹgẹ bi ''aṣiṣe nla to buru jai.''
''Gẹgẹ bi mo se sọ lawọn ipade wa to waye, lẹẹkan si mo fi itiju ati ibanujẹ mi han, ti mo si tọrọ aforijin lati inu ọkan mi wa''
''Laipẹ yii mo mọ pe maa de iwaju adajọ nla lati wi tẹnu mii''
Ohun to ṣẹlẹ ki esi iwadii to jade:
Ki wọn to gbe esi iwadii naa jade ni oṣu Kini, Poopu ti tako pe oun ba wọn kopa ninu ipade kan lọdun 1980 ti o da lori iwa ifipabọmọde lopo to waye ni Munich.
Ṣugbọn nigba ti esi yii jade, Poopu palu ẹnu da, to si ni lootọ ni oun kopa ninu ipade naa.
Akọwe Poopu nigba naa, Archbishop Georg Ganswein, sọ pe igbagbe lo mu kawọn ma ṣe sọ pe o wa nibẹ ati pe awọn ko mọọmọ ṣe bẹẹ.
Poopu Benedict mẹnu ba ọrọ yii ninu iwe rẹ to kọ, to si ni afojufo yii fọwọ kan oun lẹmi nitori o ni ''tabuku si mi tawọn mii, o si sọ pe opurọ ni mi.''
Poopu Benedict ni Poopu akọkọ to kọwe fipo silẹ:
Ninu akọsilẹ itan ijọ Aguda, Benedict ni Poopu akọkọ ti yoo kọwe fipo silẹ lati nkan bi ẹgbẹta ọdun.
Ikọwefiposilẹ rẹ waye lọdun 2013, to si ni ailera lo mu ki oun kọwe fipo silẹ.
Lati igba to fi ipo yi silẹ lo ti n gbe igbe aye jẹjẹ ni Vatican, ti wọn si da lọla gẹgẹ bi poopu emeritus.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwa ifipabọmọdelopọ lati ọwọ awọn alufaa ijọ jẹ ohun to tabuku ijọ Aguda tawọn eeyan kaakiri agbaye si ti bẹnu atẹ lu.
Lẹyin ti Benedict kuro lori oye, Poopu Francis to gba ipo lọwọ rẹ ṣe agbekalẹ awọn ofin lile kan, eleyi ti yoo dena iru iwa bayi.
Lara rẹ ni eleyi to sọ di iwa ọdaran pe ki alufaa fipa ba ọmọde lopọ. Bakan naa lo ni wọn ko ni bo aṣiri eyikeyi alufaa to ba ṣe aṣemaṣe pẹlu awọn ọmọde nile ijọsin.


















