Pápà mímọ́: Ọlọ́run yóò fi ẹ̀mí ìbágbépọ̀ rere sí Nàíjíríà

Aworan Popu Francis

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Popu gbarata, tàwọn ọmọlẹ̀yin kírístí sì n fẹhọnu lori ìsekúpani ní ípínlẹ̀ Benue

Olori Ijo Aguda ni agbaye, Pápà mímọ́ Francis, ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu si ile ijọsin kan nibi ti wọn ti pa Fada meji ati awọn olujọsin ni ipinlẹ Benue, lorilẹede Naijiria.

Iwe Iroyin Associasted Press sọ wipe, Poopu naa sọrọ lori isekupani lorilẹede Naijiria nibi apejọ to waye ni gbagede Saint Peters Square ni ilu Romu.

Adari ijọ Àgùdà ni agbaye naa wá gbadura fun awọn ẹlẹsin Kiristi lati ri itunu ati ibagbepọ rere lasiko yii.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amin iyasọtọ kan

Ọrọ Poopu naa waye ni asiko ti Ajọ ọmọ lẹyin Kiristi lorilẹede Naijira, CAN, kesi awọn Kiristẹni lati tu jade lọwọọwọ, lati fẹhọnu han lori isekupani awọn onigbagbọ kaakiri orilẹede Naijiria.

Aarẹ ẹgbẹ CAN ni Naijiria, Ẹniọwọ Ọlasupọ Ayọkunle sọ wipe, afojusun iwọde naa ni lati kesi ijọba apapọ ati ajọ eleto aabo lorilẹede Naijiria, lati wa ọna abayọ si ọgọọrọ ẹmi ti awọn Fulani darandaran n pa ní aarin gbungun orilẹede Naijiria.