Bunmi Akinnanu: Ọlọ́run kìí fún èèyàn méjì ní orin ẹ̀mí kan ṣoṣo, ẹ jẹ́ ká ṣe sùúrù

Àkọlé fídíò, Bunmi Akinnanu: Ọlọ́run kìí fún èèyàn méjì ní orin ẹ̀mí kan ṣoṣo, ẹ jẹ́ ká ṣe sùúrù

Gbajugbaja akọrin ẹmi kan, Bunmi Akinnanu to kọ orin Omije Oju mi n beere aanu rẹ, ti ke si awọn akẹẹgbẹ rẹ lati mase da orin ẹmi papọ mọ orin aye.

Akinnanu, lasiko to n ba BBC Yoruba fi ọrọ jomitorro ọrọ lo gbe imọran yii kalẹ, to si tun woye pe o yẹ ki orin aye wa ni ẹgbẹ kan ni, ki orin ẹmi naa si wa ni ẹgbẹ kan.

O ni orin aye ati orin ẹmi ko jọ ara wọn rara, iyatọ nla lo si wa ni aarin wọn.

Bakan naa lo tun salaye pe o yẹ ki awọn olorin ẹmi se suuru fun ara wọn lori bi wọn se maa n kọrin ti ẹlomiran ti kọ, ti wọn yoo si ni Ọlọrun lo dijọ fun awọn mejeeji ni imisi orin naa.

“Ọlọrun kii fun eeyan meji ni imisi orin kan soso, awa lo yẹ ka se suuru fun ara wa.

Kekere ni mo ti bẹrẹ orin kikọ nin u sọọsi:

Nigba to n salaye bo se di akọrin ẹmi ti aye n tẹwọgba, Bunmi Akinnanu salaye pe inu ẹgbẹ akọrin ọmọ ni oun wa ninu ijọ ECWA to wa ni Mushin.

O ni awọn lo sawari talẹnti tuntun ninu oun, ti wọn si si ri pe oun le kọrin, lẹyin igba naa ni oun lọ si ẹgbẹ akọrin fun awọn agbalagba.

Omije Oju mi ni inu ẹgbẹ akọrin agba yii ni oun ti ri pe oun naa le fi orin ẹmi jẹun.

Iyatọ wo lo wa laarin awọn akọrin ẹmi ode iwoyi ati ti atijọ:

Akinnanu, lasiko to n sọrọ lori isesi ati ihuwasi awọn akọrin ode iwoyi si ti atijọ, o salaye pe isesi awọn akọrin ẹmi lode oni yatọ pupọ si ti awọn iya to n kọ orin naa laye atijọ.

“Iwa ta ba lọwọ awọn iya wa laye atijọ kọ ni a n hu lode oni nitori iyatọ nla lo wa nibẹ.

Amọ odabi ẹni pe a tun ti n pada lọ si ti atij nitori gbogbo wa la ti mọ bayii pe ba se da gbogbo rẹ pọ nigba yẹ, ta n lu alujo kiri ti yatọ.

Ẹni to gbe igbagbọ dani, ko gbe dani, ẹni to si gbe ti aye dani, ko di mu nitori ko jọ ara wọn rara.

Maa ri awọn ẹlomiran, wọn yoo maa lo ‘slang’ aye lorisirisi, maa kan wo pe se eleyi jọ orin ijọba ọrun bi.”

Ipe ni orin ti mo n kọ, kii se ẹgbẹ akọrin, n ko fi ijọ ECWA silẹ o

Bunmi Akinnanu tun salaye fun BBC Yoruba pe oun si wa ninu ijọ Ecwa lodi si ero awọn eeyan pe oun ti fi ijọ naa silẹ.

O salaye pe ipe lati ọdọ Ọlọrun ni orin ti oun nkọ, o si yatọ si akọrin inu ijọ lasan.

“Lootọ ni Ọlọrun fa mi dide laarin ECWA amọ wọn ri pe oun to wa ninu mi tobi pupọ.

N ko sọ pe ko si wahala laarin wa amọ Ọlọrun ti yanju gbogbo, ti wọn si ti fi mi silẹ.

Koda, ti wọn ba fẹ se ajọdun, wọn maa n ransẹ pe mi lati wa kọrin fun wọn.”

Bawo lo se yẹ ki isesi olorin ẹmi jẹ?

Bunmi Akinnanu ni o yẹ ki akọrin ẹmi maa ni itẹriba fun awọn to ba niwaju, ko si mase gbe igbesẹ lati bi ẹnikẹni subu.

O ni bi wọn ba se ri Akọrin ẹmi, lo yẹ ki wọn daa mọ pe akọrin ẹmi ni, lai si igberaga nibẹ.

O wa dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ pe wọn seun, wọn ku atilẹyin oun nitori naira kan ati meji ti wọn n na fun oun, lo gba akisa kuro lọrun oun.