Glorious Twins: Taiwo àti Kehinde Ekundayo ní ọ̀dọ́ ìyá àgbà ní àwọn ti gba ẹ̀bún orin kíkọ

Àkọlé fídíò, Glorious Twins: Taiwo àti Kehinde Ekundayo ní ọ̀dọ́ ìyá àgbà ní àwọn ti ẹ̀bún orin kíkọ

Yoruba ni ọmọ ti yoo ba jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹnu samusamu.

Bẹẹ ni ọrọ awọn ọmọ ibeji ologo yii ri, Taiwo Ati Kehinde Ekundayo, ti ọpọ eeayn mọ si Glorious Twins.

Ọmọ ọdun mẹta ni awọn ọmọ mejeeji yii ti bẹrẹ si safihan si orin kikọ amọ wọn ko bẹrẹ si ni kọrin titi di igba ti wọn pe ọmọ ọdun mẹwa.

Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, Taiwo ati Kehinde Ekundayo ni ọmọ ẹgbẹ akọrin ni baba ati iya awọn ninu ijọ Celestial kan.

Amọ wọn fikun pe ọdọ mama agba ti awọn gbe, to n lọ sinu ijọ aladura CAC, ni awọn ti mu ẹbun orin kikọ naa.

Bakan naa ni wọn salaye pe awọn ẹsẹ adura orin inu ijọ CAC ni awọn ti maa n ri imisi orin kikọ ti awọn n gbe sita.

Taiwo nifẹ lati di agbẹjọro nigba ti Kehinde fẹ di dokita ti yoo maa gba ẹmi eeyan la.

Awọn ibeji ologo yii ti gbe awo orin jade, ti wọn si ti se ere fun awọn eeyan jankanjankan bii Ọọni tilu ile Ifẹ ati Ọmọọbabinrin Kolade, tii se Iyalaje ilẹ Yoruba.