Sunday Igboho: Timi Orokoya ní orin Iléyá tí òun kọ lọ́dún 28 sẹ́yìn, ló padà wá ṣẹ báyìí

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Timi Orokoya ní orin Iléyá tí òun kọ lọ́dún 28 sẹ́yìn, ló padà wá ṣẹ báyìí

Yoruba ni ọrọ agba, bi ko sẹ ni owurọ, yoo sẹ ni ọjọ alẹ.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu akọrin ẹmi nni, Timi Orokoya to kọ orin Ileya ni ọdun mejidinlọgbọn sẹyin, ti awọn ọrọ inu orin naa si n sẹ lọwọ lasiko yii.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Orokoya ni ọpọ ohun orin naa ni awọn ajijagbara to n pe fun Yoruba Nation ti yipada.

O ni ileya ti oun n sọ nigba naa, ni oun fi n pe awọn eeyan pada si ọdọ Ọlọrun ati ijọba ọrun.

Nigba to n sọrọ lori Sunday Igboho, Orokoya ni ohunkohun ko gbọdọ se ajijagbara naa nitori ija ilu lo n gbe.

O wa ke si awọn asaaju ilẹ Yoruba lati dide gbeja Sunday Igboho nitori bi ohun to n beere fun ba dohun tan, kii se oun nikan ni yoo jẹ anfaani rẹ.

Akọrin ẹmi naa ni Alọrun le lo ẹnikẹni lai naani pe boya oogun dundun lo n lo nitori ọpọ awọn ẹlẹsin mii naa n lo dudu yii.

O wa gba ijọba nimọran lati tete wa idahun si ọpọ ohun ti Sunday Igboho n beere, ki alaafia le jọba.