Plights of Widows in Nigeria: Abosede Ilori ní N16,000 ni òun ń gbà fi tọ́jú ọmọ méjì

Àkọlé fídíò, Plights of Widows in Nigeria: Abosede Ilori ní N16,000 ni òun ń gbà fi tọ́jú ọmọ méjì

Kii se ohun to dara lati jẹ opo, ka maa sẹsẹ sọ pe ki obinrin tabi ọkunrin di opo ni kekere.

Se itọju awọn ọmọ la wo ni tabi ti opo gangan ti ko ni olutọju mọ abi ti gbigbọ bukata inu ile ti ko to nigba ti oju mẹrin n pese owo ninu ile, to wa di ti oju meji.

Bi ọrọ se ri gan ree pẹlu abilekọ kan, Abosede Lydia Ilori to di opo ni kekere lai pe ẹni ogoji ọdun, to si padanu ọkọ rẹ ni ọsẹ meji pere to bi ọmọ keji.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ nipa bo se padanu ọkọ rẹ, Segun, lairo tẹlẹ, Abosede ro, ilẹ kun, to fi mọ bi igbe aye se nira fun pẹlu ọmọ meji ti ọkọ rẹ fi silẹ fun lati maa tọju.

Burẹdi ni ọkọ mi lọ ra ni alẹ ti wọn si sa pa:

Nigba to n salaye bi ọkọ rẹ se ku, Abosede ni burẹdi ni ọkọ oun l ra ni alẹ nibi ti ko jinna sile ti awọn n gbe.

O ni isẹlẹ naa waye ni ọsẹ kan pere lẹyin ti awọn se ikomọjade ọmọ rẹ keji to bi fun ọkunrin naa.

O ni sadede ni awọn eeyan kan n gba geeti ile awọn, ti oun si ro pe awọn adigunjale ni wọn fẹ wọle.

“Ẹru ti ba emi ati aburo ọkọ ta wa ninu ile, ti a si kọ lati si geeti fun wọn tori a lero pe awọn adigunjale lo de lai mọ pe aajo ọkọ mi ni wọn wa se.

Se ni awọn eeyan naa fi tipa si geeti wa, ti wọn si n pariwo pe ki n jade, wọn ti sa ọkọ mi.

Se ni mo ba ọkọ mi nilẹ, to n japoro, ta si gbe digba-digba lọ sile iwosan fun itọju nitori ẹjẹ ti bo gbogbo ara rẹ.”

Ki lo sẹlẹ nile iwosan ti wọn gbe Segun lọ?

Abosede salaye pe ẹyin ni wọn ti sa ọkọ oun ni ada, ti dokita si ni o ti se akoba fun egungun ẹyin rẹ.

O ni ọkọ oun ko le gbe ọwọ ati ẹsẹ lati rin nile iwosan lati igba ti awọn ti gbe de ibẹ, to si n jẹ irora.

“A se isẹ abẹ fun, ti oju egbo ẹyin rẹ si jinna amọ sibẹ se lo n pariwo pe oju egbo to ti jinna naa n ta oun.

Eyi si lo mu ki ọpọ eeyan maa lero pe o seese ko jẹ pe kii se ada lasan ni wọn fi sa ọkọ mi nitori irora naa pọ̀.

Nigba to di osu kẹsan ati ọjọ kan ti ọkọ mi de ile iwosan, o ki aye pe o digbose.”

Iru eeyan wo ni oloogbe Segun jẹ si iyawo ati ọmọ:

Aya oloogbe naa ni eeyan daadaa ni ọkọ oun, baba rere si ni pẹlu si awọn ọmọ r.

O ni ọkọ oun kii fi ọrọ oun ati awọn ọmọ rẹ sere, to si maa n se ohun gbogbo lati tẹ oun lọrun.

Bakan naa lo sọ pe oun ko le sọ pe ọkọ oun sẹ awọn eeyan to saa ni ada naa nitori to ba jẹ pe ọkọ oun ni ede aiyede pẹlu ẹnikẹni, yoo dele sọ fun oun.

O ni ọkọ oun kii fi ohunkohun pamọ fun oun, ko si si ohun to sẹlẹ, ti kii sọ fun oun.

Bawo ni igbe aye se ri fun Abosede atawọn ọmọ lẹyin iku oloogbe?

Abosede ni nnkan ko rọrun rara lẹyin ti ọkọ oun ku tan, ti igbe aye si nira pupọ lati gbe.

O sọ pe oun atawọn kuro nile ti awọn n gbe pẹlu ọkọ oun, ti oun si ko tọ iya ọkọ oun lọ.

Abosede ni ile ẹkọ adani kan ni oun ti n sisẹ olukọ, ti oun si n gba ẹgbẹrun mẹrindinlogun naira losu.

“Ajọ ni mo n da, ti mo si n gba ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ni ẹẹmẹta lọdun.

Eyi ni mo fi n san owo ile ẹkọ awọn ọmọ amọ aye ko rọrun rara lati gbe fun opo ti bukata si pọ.”

Se opo kekere yii setan lati fẹ ọkọ miran?

Abosede ni lootọ o seese ki oun ni ọkọ miran nigba to ba ya nitori ọjọ ori oun si kere jọjọ.

Amọ o ni ẹni ti yoo ba fẹ oun gbọdọ setan lati gbọ bukata lori awọn ọmọ mejeeji ti oun bi naa nitori oun ko le ko ọmọ oun silẹ fun ẹnikẹni lati lọ sile ọkọ tuntun.