Military Coup In Africa: Àkójọpọ̀ ìròyìn rèé lórí bí ìlú kò ṣe rọgbọ ní DR Congo

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn oniwadii lorileede DR Congo sọ pe awọn ni ẹri to lamilaaka eleyi to tọka si igbesẹ tawọn kan n gbe lati da omi alaafia ilu ru.
Agbẹnusọ aarẹ orileede naa lo fi ọrọ yii lede.
Ninu atẹjade kan to ka lori ẹrọ amohunmaworan lorilẹede naa lọjọ Iṣẹgun, Kasongo Mwema sọ pe awọn ko ni faaye gba iru igbesẹ to le ṣe akoba feto ijọba awarawa.
- Olórí ìgbìmọ̀ aláṣẹ́ tó ga jù ní Sudan, Ọ̀gágun Burhan ti kéde ìlú ò fararọ
- Ète ìdìtẹ̀ gbàjọba forí sánpọ́n ní Sudan
- Àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Àdúláwọ̀ fòfin de Burkina Faso lórí ìdìtẹ̀gbàjọba
- Ta ni Idriss Deby tí kò bá tún gorí àlééfà ipò aarẹ Chad lẹ́ẹ̀kẹfà tó wá ṣaláìsí yìí?
- Kí ló dé tí ológun ń yẹ àga ìjọba mọ́ alágbádá nídìí l‘Áfíríkà?
- Àjọ AU fajúro lórí ọwọ́jà ìdìtẹ̀ gbàjọba tó ń wáyé nílẹ̀ Afrika
- Pervez Musharraf, Àarẹ ológun Pakistan nígbà kan rí gbọ́jọ́ ikú
Ikede naa lo n waye lẹyin ti wọn mu oluranlọwọ pataki si aarẹ Félix Tshisekedi lori ọrọ aabo, François Beya lọjọ Abamẹta.
Eleyi naa si ṣe deede igba ti aarẹ n kopa nibi ipade apero ajọ iṣọkan ilẹ Afrika AU ni olu ilu orileede Ethiopia, Addis Ababa
A gbọ pe mimu ti wọn mu amugbalẹgbẹ aarẹ yii ti fa iwọde, tawọn ọmọ ẹgbẹ aarẹ kọọkan naa si tu sita lati fẹhonu han.
Lọjọ Iṣẹgun, agbẹnusọ aarẹ sọ pe iwadii n tẹsiwaju ati pe gbogbo nkan ti pada sipo.
Bi ijọba ati ileeṣẹ aarẹ se dakẹ lori ọrọ naa lati ọjọ Abamẹta ti mu ki ibẹru-bojo wa nipa pe nkan ko rọgbọ pẹlu iṣakoso ilẹnaa.
Ati arakunrin Beya ati agbẹjọro rẹ, ko si ẹni kankan to ti sọrọ nipa iṣẹlẹ ọhun.
Ifditẹgbajọba n gogo nilẹ Afirika lẹnu ọjọ mẹta yii:
Bi a ba foju wo o, awọn orileede Afrika lẹnu ọjọ mẹta yii, paapa awọn olori orilẹede n jaya lori iṣẹlẹ iditẹ gbajọba.
Ni meni meji, ba ba ni ka kaa, a ti ri nkan bi iditẹ gbajọba mẹta si mẹrin to waye lai fi awọn ifipagbajọba to pẹlu rẹ naa kun.
Burkina Faso, Guinea to fi mọ orileede Mali wa lara awọn orileede ti iditẹgbajọba ti waye lẹnu lọọlọ yii.
Ọrọ naa le debi pe awọn ẹgbẹ to wa fun idagbasoke ilẹ Afrika bi AU ati ECOWAS n bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yii.
Koda, ipade ti aarẹ Félix Tshisekedi lọ ni Ethiopia, ọrọ naa jẹyọ nibẹ, ti awọn olori si pa ẹnu pọ sọ pe awọn ko faramọ asa dida omi oṣelu awarawa ru.
Ifipagbajọba lagbaaye:
Lagbaaye, ifipagbajọba ti ṣẹlẹ nigba 476 lati ọdun 1952.
Afirika ni iṣẹlẹ ifipagbajọba ti pọju lagbaaye.
Ilẹ South Amẹrika lo tun tẹ le Afirika, igba marun un le laadọrun ni ifipagbajọba ṣẹlẹ, igba ogoji si lo kẹsẹjari.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni bi ogun ọdun sẹyin, iṣẹlẹ ifipagbajọba ti dinku nilẹ South America.
Lọdun 2002 nigba ti irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ waye lorilẹede Venezuela nigba ti awọn ologun fẹ ditẹ gbajọba aarẹ Hugo Chavez ṣugbọn wọn kuna.



















