Coups in Africa: Àjọ AU fajúro lórí ọwọ́jà ìdìtẹ̀ gbàjọba tó ń wáyé nílẹ̀ Afrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ isọkan ilẹ adulawọ, African Union, ti bẹnu atẹ lu ọwọja iditẹ gbajọba to n waye lẹnu lọọlọ yii.
Gbogbo awọn olori ilẹ Afrika to wa nibi ipade apero ajọ naa to n waye ni Ethiopia, ni ko ṣẹnu ku lati bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yi.
Kọmisana feto oselu, alaafia ati aabo fun ajọ naa, Bankole Adeoye lo fidi ọrọ yi mulẹ.
Adeoye sọ pe ajọ AU ko faaye gba ki awọn ologun maa gba ijọba fi ṣe faaji ni orilẹede koowa wọn, tori naa, lawọn ṣe ni ki orilẹede mẹrin lọ rọọkun nile laarin ọdun kan sẹyin.
Awọn kan n woye boya aṣẹ lọ rọọkun nile ti ajọ AU pa yoo nipa kankan lori awọn ologun to gbajọba ni Mali. Guinea, Sudan ati Burkina Faso.
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ, Bankole sọ pe ko sootọ ninu ọrọ tawọn kan n sọ pe AU ko se nkankan lori ogun to n lọ lọwọ ni Ethiopia.
Orileede Ethiopia ni olu ileesẹ African Union wa.
O ni lati ọjọ ti ọrọ naa ti bẹrẹ lawọn ti dasi ati pe awọn n ṣiṣẹ lati ri pe wọn pẹtu saawọ naa.












