Military coup in Burkina Faso: Ọmọ ogun gbàjọba ni Burkina Faso, wọ́n ti gbogbo ibodè orílẹ̀-ède náà pa

Oríṣun àwòrán, @disclosetv
Àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Àdúláwọ̀ fòfin de Burkina Faso lórí ìdìtẹ̀gbàjọba
Àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Àdúláwọ̀ (AU) ti gbégi dínà àjọṣepò pẹ̀lú orílẹ̀ èdè Burkina Faso lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tí àwọn Ológun gbàjọba ní orílẹ̀ èdè náà.
Àjọ náà ní Burkina Faso kò ní ẹ̀tọ́ láti kópa nínú gbogbo ètò àjọ náà àyàfi tí àwọn ológun bá dá ìjọba padà fún àwọn alágbádá.
- Àwùjọ àgbáyé, ẹ ṣèrànwọ́ fún Burkina Faso kó le borí ìṣòro - Olórí ìjọba ológun
- Sanwo-Olu kède iye tí àwọn aráàlú yóò máa wọ ọkọ̀ ojú irin ayára bí àṣá tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ́ rà
- Osun la fẹ́ kí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ti wáyé, kìí ṣe Abuja - Mọ̀lẹ́bí yarí
- Ilé aṣòfin n rẹkẹ, Boris Johnson takú, tá ní yóò bóri lórí awuyewuye ''party'' ọjọ́ ìbí?
- Òkú kú ní ẹ̀ẹ̀kejì nígbà tí òkú 400 jóná ráúráú ní mọ́ṣúárì, ẹbí bú sẹ́kún lẹ́ẹ̀kejì
- Dangote, má ṣe dáwọn ọ̀dọ́ tó ní kó dupò ààrẹ lọ́dún 2023 lóhùn o- Shehu Sani

Oríṣun àwòrán, others
Àjọ ECOWAS tó ti ṣaájú fi òfin de Burkina Faso lọ́sẹ̀ tó kọjá ti rán ikọ̀ kan lọ sí olú ìlú orílẹ̀ èdè náà, Ouagadougou báyìí.
ECOWAS yóò darapọ̀ mọ́ ikọ̀ àjọ ìṣọ̀kàn àgbáyé láti jíròrò pẹ̀lú àwọn ológun náà.
Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin ni Burkina Faso?
Àwọn ọmọ ogun ti dìtẹ̀gbàjọba ni Burkina Faso
Ileeṣẹ ọmọ ogun Burkina Faso ti gba ijọba lorilẹ-ede naa.
Awọn ọmọ ogun ilẹ naa lo fi ikede ọhun sita ninu igbohunsafẹfẹ ori tẹlifiṣọn kan, nibi ti wọn ti kede pe awọn ti gbe iwe ofin orilẹ-ede naa ti sapa kan, awọn si ti gbe gbogbo ẹnubode orilẹ-ede ọhun ti pa.
Wọn fi kun pe awọn ti wọgile ile igbimọ aṣofin orilẹ-ede naa awọn si ti tu ijọba alagbada to wa nilẹ tẹlẹ ka.
Eyii to n tumọ si pe ijọba ologun lo wa lode bayii ni Burkina Faso.
Ṣaaju ni awọn araalu ti kọkọ gbọ iro ibọn nitosi ile Aarẹ Roch Marc Christian Kaboré, lẹyin naa ni ni awọn ọmọ ogun ọhun fi Aarẹ naa si ahamọ.
Ẹwẹ, ajọ iṣokan agbaye, UN, ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ṣé ìdìtẹ̀ gbàjọba ló ń wáyé ní Burkina Faso àbí kí ló gbé ológun jáde?
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ti ni awọn ologun to n ditẹ gba ijọba ni orilẹede Burkina Faso, ti fi aarẹ ilẹ naa, Roch Kabore si ahamọ.
Bakan naa ni awọn ologun aditẹ gbajọba naa la gbọ pe wọn n beere pe kawọn ọgagun lorilẹede naa lọ rọkun nile na, ti wn si n fẹ awọn ohun eelo si lati doju ija kọ awọn agbesunmọmi.
Ijọba orileede Burkina Faso ti wa kede iṣede laarin aago mẹjọ alẹ si marun un abọ owuro lẹyin ti iroyin gbode pe iditẹ gbajọba ti waye nilẹ naa.
- Àwọn ológun gbàjọba ní orílẹ̀-èdè Guinea
- Olórí ìgbìmọ̀ aláṣẹ́ tó ga jù ní Sudan, Ọ̀gágun Burhan ti kéde ìlú ò fararọ
- Ọmọ ogun ilẹ̀ mẹ́tàléláàdọ́ta ni wọ́n ti pa nínú ìkọlù Mali
- Wo ìdí tí ECOWAS fi dá Mali dúró, tó tún fún àwọn ológun ní gbèdéke láti gbé ìjọba sílẹ̀
- Ọwọ́ tẹ arúfin ogun Timbuktu
- Evariste Ndayishimiye di ààrẹ tuntun lórílẹ̀èdè Burundi
Ṣadede ni iro ibọn bẹrẹ si ni dun lọjọ Aiku lẹgbẹ ile aarẹ Roch Kabore ni Ougadougou tii ṣe olu ilu ilẹ naa.
Bakan naa lawọn kan n yin ibọn kikankikan lawọn ibudo ọmọ ogun ilẹ naa ni Ougadougou.
Igbesẹ wo ni awọn ọmọ ologun yii gbe lati fipa gba ijọba?
Lọjọ Aiku taa n wi yi, awọn alatilẹyin ọmọ ogun ti wọn ni wọn fipa gbajọba yi n gbegi dina kaakiri adugbo ki awọn ọlọpaa to tu wọn ka.
Ohun taa n gbọ bayi ni pe aarẹ Roch Kabore wa ni ahamọ to si ṣe pe orukọ ọgagun kan Paul Sandaogo Henry Damiba lawọn eeyan n ran lẹnu.
A tun gbọ pe o ṣeeṣe ki a atẹjade kan lori ibi tọrọ de duro desi eti igbọ awọn eeyan laipẹ yi.
Ajọ ECOWAS ti da si ọrọ yi nipa atẹjade ti wọn fi sita pe ki awọn ọmọ ogun yi ṣe ijiroro pẹlu awọn alaṣẹ.
Titi di ba ṣe n ko iroyin yi jọ, ko si ẹni to le sọ pato nkan to n ṣẹlẹ ati ẹni ti akoso orileeede naa wa ni ikapa rẹ.
Ijọba ni kawọn ile ẹkọ wa ni titi pa:
Lori ileeṣẹ ẹrọ amounmaworan orileede Burkina Faso ni wọn ti ka atẹjade kan to sọ pe konile o gbele yoo bẹrẹ laarin ago mẹjọ alẹ si ago marun un abọ owurọ.
Nibi ọrọ de duro, ileeṣẹ to n ṣoju ilẹ Farance ti kilọ fawọn oṣiṣ wọn lati yago fun irin al ki wn si deju mọ inu ile wọn.
Aṣoju France ni Burkina Faso, Luc Hallade sọ pe ọrọ ko ti ni iyanju ati pe awọn yoo maa fawọn eeyan wọn nilẹ naa ni iroyin bi nkan ba ṣe n lọ si.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ki lo ti ṣẹlẹ latẹyinwa:
Ni nkan bi ọsẹ kan sẹyin ni wọn mu awọn ọmọ ogun mọkanla kan pe wọn n gbero lati ditẹ gbajọba.
Ni Burkina Faso, inu awọn araalu ko dun si bi ipa ijọba aarẹ Kabore ko se ka ikọlu tawọn alakatakiti ẹsin Islam kan n se ọsẹ nilẹ naa.
Eyi to wa fọju ọrọ pọ ni iṣẹlẹ to waye loṣu Kọkanla nigba tawọn afurasi alakatakiti ẹsin kan pa eeyan mẹtalelaadọta.
Eleyi mu ki awọn eeyan maa sọ pe o ṣeeṣe ki iditẹ gbajọba waye nibẹ gẹgẹ bo ti ṣe ṣẹlẹ ni Mali loṣu Karun ọdun to kọja.
Lọjọ Abamẹta to kọja, ọgọọrọ awọn eeyan ni ijọba mu ni Ougadougou tori wọn se iwọde tako aikapa ijọba lati koju awọn agbebọn wọnyi.
Ta ni Roch Kabore to wa ni ahamọ?
Aarẹ Kabore wọle idibo aarẹ lọdun 2015. Ṣaaju lo ti ṣiṣẹ nile ifowopamọ to si tun ti jẹ olootu ijọba nilẹ Burkina Faso.
Ibo to gbe wọle jẹ akọkọ iru rẹ lẹyin ti aarẹ tẹlẹ to pẹ lori oye, Blaise Compaoré sa lẹyin ti araalu ṣe iwọde le kuro lori alefaa.





















